You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Jẹẹsí Eagles: Bí wọ́n ṣe ṣíi ní London náà ló tán lórí igbá
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1
Àwọn ọmọ orílẹ̀-ede Naijiria ati àwọn aláwọ̀ funfun, ti ya bo iléeṣẹ́ Nike tí ó ṣe aṣọ egbẹ́ agbáọ́ọ̀lù Naijria, ní kété tí wọn ṣí aṣọ náà ní iléeṣẹ́ wọn tí ó wà ní London.
A tí lẹ̀ gbọ́ pé, èrò tí ó wá sí ṣọ́ọ́bù Nike náà láti ra jẹẹ́sí ní ìgbaradì fun ìdíje ife àgbáyé pọ̀ tó bẹ̀ẹ̀, tí wọ́n tò láti àdúgbò kan sí òmíran.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Iléesẹ́ Nike sọ lójú òpó ìkànsíraẹni Twitter wọn pé lóótọ́ ni ajé bu igbá jẹ.
A gbọ́ pé, aago mẹ́jọ àárọ̀ ni wọn ṣí jẹẹsí náà, ní wákàtí péréte lẹ́yìn náà, ni Nike ba sọ pé wọn ti ra gbogbo jẹẹsí tí ó wà nílẹ̀ tán.