Amòfin: Nínà ojoojúmọ́ lé mu kí ìyàwó pa ọkọ rẹ̀

Kìí ṣe tuntun fún tọkọ-taya láti ní gbólóhùn asọ̀ láàrin ara wọn, ṣùgbọ́n kàyéèfì tó wà níbẹ̀ ni pe, kí irú àáwọ́ bẹ̀ maa yọrí sí ikú tàbí ìfarapa.

Láyé ìgbà kan, ọkùnrin ni a ṣábà maa n gbọ́ pé, ó lu ìyàwó rẹ̀, ṣùgbọ́n lóde òní, ìròyìn nípa àwọn òbìnrin tó n lu ọkọ wọn nàá tí n jáde.

Láti bi i ọdún mélòó sẹ́yìn, ni ìròyìn ń gbalẹ̀ kan nípa bi ọkọ tàbí ìyàwó ṣe n pàdánù ẹ̀yà ara wọn lásìkò tí ìjà bá n wáyé láàrin tọkọ-taya, tí àwọn mìí tilẹ̀ n pàdánù ẹ̀mí wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amòfin kan tó tún jẹ́ ajàfẹ́tọ̀ àwọn obìnrin, Abiade Abiala, nígbà tó n bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀, ṣàlàyé oríṣiríṣi ìwà ipá tó wà.

Àwọn ohun tó ń fa ìwa ipá

  • Sísọ ọ̀rọ̀ kòbákùngbé síra ẹni, tàbí fífi ọ̀rọ̀ èébú ránṣẹ́ sí òbí ọkọ tàbí ìyàwò ẹni.
  • Àì fi owó oúnjẹ sílẹ̀ fún ìyàwó nítori pé ó sẹ ọkọ.
  • Kódà, àìbìkítà fún ẹ̀tọ́ tàbí ifẹ́ inú ẹnìkejì lásìkò ìbálòpọ̀ nàá wà lára lílo ìwà ipá nínú ìgbeyàwó.
  • Ọkùnrin tó bá ní kí ìyàwó òun máà ṣiṣẹ́ tàbí tó n gba owó lọ́wọ́ ìyàwó lọ́nà àìtọ́.

Kí ló lé mú obìnrin pa ọkọ rẹ̀?

  • Kí àwọn òbí ẹni máse fọwọ́ sí kíkọ́ra ẹni sílẹ̀ lẹ́yìn tí ìgbéyàwó ti pin obìnrin lẹ́mìí.
  • Ìbẹ̀rù ojú tí àwùjọ yóò fi wo ni.
  • Obìnrin míi maa n fínnú-fíndọ̀ dúró sínú irú ìgbéyàwó bẹ̀ẹ̀ nítorí 'ẹ̀jẹ́ tí wọ́n ti bá ọkàn wọn dá pé àwọn kò ní fẹ́ ju ọkọ kan tàbí bímọ fún ju ọkùnrin kan lọ.’
  • Ìpolongo àti ìlani lọ́yẹ̀ tó ti pọ̀ si lójẹ́ kí àwọn òbinrin maa maa gbẹ̀san ìwà ipá tí ọkùnrin bá wù sí wọn.
  • Àti pé bí àwọn ìyàwó ilé nàá ti ṣe n ṣiṣẹ́ n fún wọn ní ìgboyà láti 'gbèjà' ara wọn.
  • Àti pé ọpọ̀lọpọ̀ obìnrin ti rí nkan tójú àwọn tó bá ara wọn nínú irú ìgbeyàwó bẹ́ẹ̀ n rí, ni wọ́n ṣe n fi ọ̀rọ̀ ṣe 'ẹní yára ni ògún n gbè.

Ìmọ̀ràn fún tọkọ-taya

Ó wá gba tọkọtaya ní ìmọ̀ràn pé, n ṣe ló yẹ kí ọkọ àti ìyàwó tó bá n la irú nkan bẹ́ẹ̀ kọjá wá ọ̀nà láti ṣàtúnṣe.

Àti pé, kí gbogbo ènìyàn àwùjọ mọ̀ pé, bí àwọn obìnrin nàá ti ṣe n gba ara wọn sílẹ̀, tí àwọn mì í tilẹ̀ n ṣekú pa ọkọ wọn, n fihàn pé, àsìkò ti tó láti fi òpin sí irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀, àti láti wá ọ̀nà tí nkan kò fi ní bàjẹ́ ju bóṣe wà lọ.