You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Gani Adams: 'Ìdàgbàsokè nínú ìmọ̀ ló jẹmí lógún'
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1
Ààrẹ ọ̀nà kakanfò ilẹ̀ Yorùbá, Gani Abiodun Adams, gbá ìwé ẹ̀rí nínú ìmọ̀ ètò òṣelú, (political Science) nile ìwé gíga fáfitì ti ipinlẹ Eko.
Ààrẹ sọ èyí di mímọ̀ lóri ojú òpó ìkànsíraẹni Instagram rẹ.
Ó ní òún ṣe èyí fún ìdàgbàsókè ara òun nítorí pe òún fẹ́ran ìwé kíkà púpọ.
Bákan náà ló gba ọdọ níyànjú láti múrawọn dàgbàsókè nínú ẹ̀kọ́ ohun gbogbo ti wọn ba yàn láàyò.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ọ̀pọ̀ àwọn ololúfẹ́ rẹ̀ lo sì tí ń kíi kú oríre
Kò si ohun to ni ibẹrẹ ti kii ni òpin
Oloye Gani Adams ni aarẹ ọna kakanfo tuntun fun gbogbo ilẹ Yoruba.