You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Fayoṣe: Iná tí kò ní pẹ̀ ẹ́ kú ni àṣeyọrí Fayẹmi
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1
Gómìnà ìpìnlẹ̀ Èkìtì,ti ní kí Kayọde Fayẹmi maa tì i dun nú fún bó ṣe borí nínú ìdìbò abẹ́lé APC.
Ayọdele Fayoṣe, tó sọ̀rọ̀ nàá nínú ìkéde kan tó fi síta lójú òpó Twitter rẹ̀ ní ''iná tí yòó kú lọ́ja kẹrìnlá, oṣù Keje ní àṣeyọrí Fayẹmi.
Ó ní ''kí Fayẹmi ní ìrètí wí pé ìjákulẹ̀ rẹ̀ nínú ètò ìdìbò tó n bọ̀ yóò burú fun un ju ti 2014."
Fayẹmi tó jẹ́ mínísítà fún ìdàgbàsókè ìwakùsà àti ìrìn rírọ́ ló gbégbá orókè nínú ètò ìdìbò abẹ́lé ẹgbẹ́ All Progressives Congress, tó wáyé lọ́jọ́ Àbámẹ́ta láti yan ẹni tí yóò ṣojú ẹgbẹ́ nàá nínú ètò ìdìbò sí ipò gómínà tí yòó wáyé lọ́jọ́ kẹ̀rìnlá, oṣù Keje, 2018.