You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ó nídìí tí Sẹ́nétọ̀ Melaye fi fo bọ́ọ́lẹ̀ nínú ọkọ̀ ọlọ́pàá
Njẹ́ ó mọ ìdí tí Sẹ́nétọ̀ Dino Melaye ṣe fò bọ́ sílẹ̀ nínú ọkọ̀ àwọn ọlọ́pàá?
Agbẹjọ́rò rẹ̀, Amòfin àgbà, Mike Ozekhome ní ìbẹrù fún ẹ̀mí ara rẹ̀ ló mú kí aṣòfin Melaye bẹ́ sílẹ̀ láti inú ọkọ̀ nígbà tí àwọn ọlọ́pàá fẹ́ gbé e lọ sí ìlú Lokoja.
Amòfin Ozekhome ní àwọn ọlọ́pàá yín tajútajú si aṣòfin náà ló fi fò bọ́ sílẹ̀ kí ó tó máa sé èmí.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
O ní lẹ́yìn tí àwọn ọlọ́pàá ti fií lọ́kàn balẹ̀ pé ìlú Àbúja ni wọn yóò ti ṣe ẹjọ́ rẹ̀ ni wọ́n bá tún pẹ̀yìndà fẹ́ máa gba ọ̀nà Lokoja lọ́sẹ̀ tó kọjá.
Síwájú ọ̀rọ̀ Ozekhome ni àwọn amúgbálẹ́gbẹ́ aṣòfin Dino ti ń sọ f'áráyé pé ọlọ́pàá ló tíì jábọ́ láti inú ọ̀kọ̀.
Aṣòfin Dino Melaye wà níléèwòsàn ìjọba nílùú Àbújá lẹ́yìn tí iléẹjọ́ ti pàṣẹ kí wọ́n fún un láàyè láti gba ìtọ́jú níléèwòsàn ńlá tó wà nílùú Àbújá.