You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọlọ́pàá Kogi: Àwọn tọ́ọ́gì Melaye yìnbọn mọ́ òsìsẹ́ wa, la se ń wa
N se ni nkan tun n gbona giri-giri fun Sẹnetọ Dino Melaye lọdọ ileesẹ ọlọpaa, kaka ki ewe agbọn aawọ rẹ ati ileesẹ ọlọpaa si dẹ, lile lo tun n le si.
Idi ni pe ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Kogi tun ti fidi rẹ mulẹ pe, ootọ ni ọrọ to n ja rain-rain nilẹ pe awọn ya bo ile Dino Melaye to wa ni ilu abinibi rẹ, Ayetoro Gbẹdẹ, nipinlẹ Kogi, lati ti tun gbe sẹnetọ naa lapan yaka.
Atẹjade kan ti Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Kogi, William Aya fisita lọjọ Abamẹta ni, oun fẹ mu Melaye nitori bi awọn janduku rẹ se yinbọn mọ ọlọpaa kan, Sajẹnti Danjuma Salihu losu keje ọdun yii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ọlọpaa ni o di dandan ki awọn tan imọlẹ si ọrọ yii niroti ikede kan ti Melaye fisita loju opo Twitter rẹ lọjọ Ẹti pe Ẹsọ gomina Yahaya Bello lo lewaju awọn eeyan kan lati wa gba ẹmi oun.
"A wa fẹ fi to araye leti pe irọ to jinna si ootọ ni ohun ti Melaye sọ yii, ero ọkan rẹ lasan ni. Koda, Kọmisọna ọlọpaa ran wa lọ si ile rẹ lati mu, amọ a ko ri mu."
Bakan naa ni ileesẹ ọlọpaa Kogi tun n na ika aleebu si Melaye pe o tun lo awọn janduku lati kọlu awọn ọlọpaa to n sisẹ wọn loju ọna Mopa si Ayetoro Gbẹdẹ
Ki lawọn iriri Dino Melaye lọwọ ọlọpaa
Láàrin àná sí oní è je ki a ṣe àgbéyẹ̀wò ohun to ti ṣẹlẹ sí Senato Dino Melaye.
Lọ̀jọ̀ ajé, awọn ilé iṣẹ ọlọpaa mu ní pápáko ofurufu Abuja nígbà tí o fe se irin-ajo lo sí Morocco.
Awon ọlọpaa tú u silẹ, O sí padà sí ilé rẹ̀.
Lẹyìn ìgbà náà, Dino fi ọrọ síta lójú òpó Twitter rẹ̀ pe àwọn ọlọpaa ti rọ̀gbà yíká ile oùn.
Kóda àwòrán àwọn aṣatipo tí wọn wà bá a kedun lórí ìṣẹlẹ náà tun jẹyọ.
Ni òwúrọ̀ ọjọ́ ìṣẹgun, ìròyìn gbálẹ̀ pé Dino ti jọ̀wọ́ ará rẹ̀ fún àwọn ọlọpaa.
Nigba tí ọsán yóò fi tó, ìròyìn bẹ̀rẹ̀ sí ní káàkiri pé àwọn ọlọpaa ti fẹ gbé Dino lo sí ilé ẹjọ́.
Kò pé sí igba naa ni àwọn fídíò bẹrẹ sí ní gba ori ẹrọ ayélujára to ṣe àfihàn Dino níbi tí o joko sí ilé láàrin ojú titi lÁbuja.
Oun ti a ri gbọ ni pe Dino kọ̀ láti tẹlé àwọn ọlọpaa lo sí Lokoja níbi tí àwọn kan ni won yóò ti ṣe àfihàn rẹ pẹlú àwọn adigunjale míràn.
Lọwọ irọlẹ la gbo pé wọn ti gbe e lo sí ilè ìwòsan Zankli, nilu Abuja ti àwòrán rẹ lori ibùsùn aláìsàn sì gbà ojú Twitter kan.
Ni báyìí ìròyìn tó tẹ wá lọwọ ni pé àwọn ọlọpaa ti ragba yíká ilé ìwòsan Zankli láti ri wí pé Dino ko sa kúrò ní bè.