You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìpínlẹ̀ Kaduna ṣọ̀fọ̀ àwọn tó kú ni Birning Gwari lọ́jọ́ Abamẹta
Opọ̀lọpọ̀ ìgbà ni àwọn oníṣẹ́ ibi yii ti kọlu Birnin Gwari, ti wọn si ti ké gbàjarè sijọba, ki gbogbo ẹ tó di ńlá lọ́jọ́ Abamẹta tó kọja ti wọn pa ènìyàn to le ni aadọta
Àwọn ìkọlù ọ̀hún ni wọ́n di ẹ̀bi rẹ̀ ru àwọn olè a-jí-máàlù kò pẹ àwọn ara abule naa ko fi aaye gba wọn lati fi ibẹ̀ ṣe ibujoko.
Ààrẹ Mùhámádù Bùhárí fi buwọ́lù ìdásílẹ̀ ọ̀wọ́ iléeṣẹ́ ọmọogun tuntun àti àwọn iléeṣẹ́ ọlọ́pàá tuntun lágbègbè Birnin Gwari ní ìpínlẹ̀ Kaduna.
Wọn ti sin òkú àwọn tó doloogbe latari ikọlu to waye gbẹyin lọjọ Abameta to jẹ ọjọ buruku èṣù gbomi mú.
Ijọba ipinlẹ̀ Kaduna ni àwọn òṣìṣẹ́ elétò ààbò yóò máa dáàbò bo àwọn ènìyàn agbegbe yii