You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wenger dágbére fún Arsenal ní pápá ìseré Emirates
Ikọ Arsenal fakọyọ pẹlu amín ayo marun un s'odo bi wọn ti se dagbere fun akọnimọọgba wọn Arsene Wenger to n lọ.
Arsenal f'agba han ikọ Burnley ninu ifẹsẹwọnsẹ to jẹ eleyi to kẹyin ti Wenger yoo jẹ oludari ikọ naa ni papa isere Emirates.
Ẹlẹsẹ ayo Pierre-Emerick Aubameyang gba ayo meji wọle ninu ere bọọlu naa.
Ọmọ Nigeria Alex Iwobi, Alexander Lacazette ati Sead Kolasinac naa wa lara awọn to gba bọọlu s'awọn ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.
Ikọ alatako Burnley ati awọn agbọọlu Arsenal se ayẹsi fun Wenger ki ifẹsẹwọnsẹ to bẹrẹ.
Wenger to jẹ ẹni ọdun mejidinlaadọrin gba ife ẹyẹ mẹwa to jọju ni ọdun mejilelogun ti o lo gẹgẹ bi akọnimọọgba Arsenal.