Amẹ́ríkà UK, France kọlu àwọn ọmọ ogun al-Assad

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Látàrí bí wọ́n se kọlu orílẹ̀èdè Syria láìpẹ́ yìí, orílẹ̀èdè Améríkà, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ̀sì ati orílẹ̀èdè Faransé ti koná ogun wọ́n sì ti gbé e ko ibi mẹ́ta kan tí wọ́n fojú sùn wípé àwọn ló kọlu orílẹ̀èdè Syria.
Ìgbésẹ̀ náà wáyé gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà àti kojú ìkọlù tó wá sórí orílẹ̀èdè Syria tó sì mú ẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Látàrí ìkọlù tó wáyé lórí orílẹ̀èdè Syria, olóòtú ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ̀sì, Theresa May sọ pé ìgbésẹ̀ orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà àti Faransé tí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sí dara pọ̀ mọ́ dá òun lójú wípé ti jíjáwé olúborí ni.
May tún sọ wípé nínú ọkàn òun, ohun tí àwọn se yìí gaan ló tọ́.
Ilé isẹ́ tó ńrí sí ọ̀rọ̀ àbò ní orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà sọ pé àwọn ìbúgbàmù náà ta bá báríkè àwọn ológun kan ní Damascus èyí tíí se olú ìlú orílẹ̀èdè Syria àtàwọn agbègbè méjì míì.

Ẹ̀wẹ̀, asojú orílẹ̀èdè Russia ní àwọn kò ní lajú 'lẹ̀ kí tàlùbọ̀ ó kó wọ̀ ọ́ pẹ̀lú ìgbésẹ̀ tí orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà àtàwọn tó kù se.








