Koko iroyin: Awuyewuye Dapchi, alaboyun tan’gbaloju nibi irọbi
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1
Eyi ni awọn akojọpọ iroyin ti toni.
'Jibiti ni iṣẹlẹ Dapchi, kii ṣe ootọ'
Oríṣun àwòrán, Reuters
Ni bayi, awọn ọmọbinrin ile-iwe ti awọn Boko Haram tu silẹ ni Dapchi, nipinlẹ Yobe ti wa ni'lu Abuja lati pade Aarẹ Muhammadu Buhari, ṣugbọn ọpọlọpọ ariyanjiyan lo wa lori itusilẹ awọn ọmọbinrin naa.
Ijọba apapọ sọ wipe awọn o san owo kankan lati gba awọn akẹẹkọ naa kuro ni igbekun Boko Haram.
Nigbati ẹgbẹ oṣelu alatako gboogi ni Naijiria, PDP sọ wipe iṣẹlẹ bi wọn se gbe awọn akẹkọ Dapchi itusilẹ wọn mu ifura lọwọ. Ẹ wo ibi fun ẹkunrẹrẹ.
Adajọ paṣẹ $25,000 fun oloyun tan fi'ya jẹ
Ile-ẹjọ kan ni orilẹede Kenya ti da ẹjọ ki ijọba o san iye ẹgbẹrun mẹẹdọgbọn owo ile Amerika, (milionu naira mẹsan) fun obinrin oloyun ti wọn fi iya jẹ ni ile iwosan ijọba lọdun marun sẹyin.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.