PDP tẹwọgba aabọ igbimọ to gbe kalẹ lati yanju aawọ

Asia ẹgbẹ oselu PDP

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Nkan o fararọ lẹgbẹ oselu PDP lati igba to ti yan awọn asaju tuntun

Igbimọ binukonu ti ẹgbẹ oselu PDP lorilẹede Naijiria gbe kalẹ lori atubọtan ibo apapọ ẹgbẹ oṣelu naa to waye losu kejila ọdun 2017 ti j'abọ iṣẹ rẹ fawọn asiwaju ẹgbẹ oṣelu naa nilu Abuja.

Gomina Seriake Dickson to lewaju igbimọ naa salaye wi pe gbogbo awọn to tọ lati pẹtu si ninu lawọn ti pẹtu si ninu atipe mimi kan o lee mi iṣọkan ẹgbẹ oṣelu naa mọ.

O ni bi awọn asiwaju ẹgbẹ oṣelu PDP ba lee ko akoyawọ pẹlu bi wọn ṣe n ṣakoso ẹgbẹ oṣelu naa, o di dandan ki ire to r'okun r'ọsa o pada wa sun ẹgbẹ oṣelu naa bọ.

"Lẹgbẹ oṣelu PDP ko si iyapa tabi iyanni ni pọṣin nitoripe aaye wa fun gbogbo eeyan lati se pọ."

Nigba to n tẹwọ gba abọ igbimọ naa, alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu PDP, Ọmọọba Uche Secondus salaye wi pe gbogbo ohun ti o ba yẹ ni ṣiṣe ni awọn asiwaju ẹgbẹ oṣelu naa yoo se lati daa awọn to fẹhonu kuro

pada.