Buhari: Ẹ fira yin jin fun idagbasoke orilẹede Naijiria

Oríṣun àwòrán, BERTRAND GUAY
Olori orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti kesi awọn ọmọ orilẹede yi , paapa awọn ọlaju, lati gbaradi fun igbesẹ fifi ara wọn jin gẹgẹ bii ipilẹ fun igbega ati idagbasoke orilẹede yi.
Aarẹ Buhari parọwa yi nigba to n sọrọ nibi ipade kan to se pẹlu awọn agbaagba nipinlẹ Katsina eyiti Gomina ipinlẹ naa, Aminu Masari ko sodi wa silu Daura lọjọ aiku, pẹlu afikun pe, ninu itan orilẹede kan, akoko wa tawọn ọmọ orilẹede ọhun gbọdọ gbagbe idẹrun tara wọn tabi se irubọ to ga julọ fun ilọsiwaju ati isọkan orilẹede wọn.
"Orilẹede Naijiria ti akoko tiwa yi nilo ifiraẹnijin latọdọ awọn eeyan rẹ, ko lee bọ lọwọ iwa ijẹkujẹ, isẹ ati osi, iwa ọdaran ati aisi idagbasoke to yẹ."
Nigba to n gbosuba fun ipejọpọ naa fun bi wọn se nsatilẹyin fun aayan ijọba rẹ lati mu agbega ba orilẹede yi, aarẹ Buhari fọwọ gbaya fun wọn pe aabo ẹmi ati dukia pẹlu eto idẹrun awọn ọmọ orilẹede yi yoo maa tubọ jẹ oun logun ni.
Wọn jẹjẹ atilẹyin wọn fun ijọba Buhari
Nigba to n sọrọ, gomina Bello Masari ni awọn agbaagba naa wa silu abinibi aarẹ Buhari lati baa kẹdun lori iku meji ninu awọn mọlẹbi rẹ.
Bakanaa ni Gomina Masari tun safihan ibanikẹdun ikọ naa si aarẹ lori ijamba alupupu ti ọmọ rẹ kan, Yusuf, ni laipẹ yi, to si dupẹ lọwọ Ọlọrun pe o da ẹmi ọmọ naa si ati bi wọn se fisilẹ nile iwosan laipẹ ọjọ.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Emir tilu Daura, Alhaji Umar Farouk ati Galadima tilu Katsina to tun jẹ aarẹ tẹlẹ fun ileẹjọ kotẹmilọrun lorilẹede yi, adajọ Mamman Nasir, naa wa lara awọn agbaagba to peju sibi ipade naa.
Wayi o, Emir tilu Maradun nipinlẹ Zamfara, Alhaji Garba Tambari, toun naa wa se abẹwo sọdọ aarẹ Buhari tun jẹjẹ atilẹyin awọn oriade fawọn ilana ati eto tijọba apapọ gbe kalẹ lọna ati mu eto idẹrun bawọn ọmọ orilẹede Naijiria.












