You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
'Nigeria Immigration Services' ṣàlàyé ìdí mẹ́rin tí wọ́n fi da òṣìṣẹ́ 8 dúró tí wọ́n si kìlọ̀ fún àwọn 18 míràn
Iléeṣẹ tó n risi wiwọle ati jijade awọn eeyan ni Naijiria, iyẹn Nigerian Immigration Service (NIS) ti sọrọ lori iroyin to gbode kan nipa awọn oṣiṣẹ ti wọn da duro lénu iṣẹ.
NIS da oṣiṣẹ mẹjọ duro ti wọn si kilọ pẹlu itanran fun awọn mejidinlogun mii pẹ ki wọn so ewe agbéjẹ́ mọwọ.
Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan awọn ti ọrọ kan naa ni pe wọn n ta iṣẹ ni ileeṣẹ ijoba naa.
Koda, wọn tun ni pe wọn n ko awọn fọọmu pamọ fun ara ilu yatọ si pe wọn n gba abẹtẹlẹ pẹlu awọn ti wọn n sa lẹnu iṣẹ oojọ wọn.
Saaju ni ẹnu ti n kun awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ yii paapaa awọn to wa ni papakọ ofurufu Murtal Muhammed International Airport ni ilu Eko.
Bayii iṣẹ ti gbe awọn osiṣẹ papakọ ofurufu Eko to le ni ọgọrun un lọ sibo miran lẹyin iwadii yii.
- Lẹ́yìn ọdún kàn, ǹjẹ́ òtítọ́ ti faráhàn lórí ikú Timothy Adegoke-
- Ẹ fí àwòrán Obasanjo sí owó pépà tí ẹ fẹ́̀ ṣe àtúnṣe sí- Atiku Abubakar
- Àwọn agbébọn tú àwọn ọmọdé mọ́kànlélógún sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Katsina
- Àwọn ilé, ilẹ̀ Ike Ekweremadu tó lé ní 40 tí EFCC gbà tí wọ́n fẹ́ tà rèé..-
- Owó Náírà tí kò lè ra búrẹ́dì ni àwọn ọ̀ga wá fẹ́ ṣé àtúnṣe si - Adeboye
- Ọlọ́pàá fí èsì ìwádìí ikú ọmọ Davido, Ifeanyi Adeleke síta..-
- Kí ló ń fa ìjà láàrin ọba Iragbiji àti Ẹ̀rọ̀ Àríkẹ́, gbajúmọ̀ Oníṣègùn ìbílẹ̀ l’Osun-
Kini o wa ninu atẹjade ti ileeṣẹ NIS fi sita?
Atẹjade ti adari ipolongo olu ileeṣẹ NIS ni Abuja fi sita lo fi ṣalaye ohun to ṣokunfa igbesẹ ileeṣẹ naa lasiko yii.
Kenneth Kure to fi ọwọ si atẹjade naa lo sọ pé igbesẹ naa waye pẹlu aṣẹ iyọnda lati ọdẹ ẹka ẹṣo ara ẹni aabo ilu Civil Defence, ẹka panapana, ẹka ileeṣẹ ọgba ẹwọn ati NIS ti a mọ si: Civil Defence, Correctional, Fire and Immigration Services Board (CDCFIB).
Kure ni pe iwadii lori ẹni marundinlogoji ni wọn ti kọkọ gbe wasiwaju igbimọ tẹẹkoto iwadii iwa ibajẹ Senior Disciplinary Committee (SDC) and Orderly Room Trial (ORT) lori oriṣiiris\ii ẹsun ti wọn fi kan wọn,
Kure ṣalaye pe lẹyin abajade ọpọlọpọ iwadii ni wọn fẹnuko pe ki òṣiṣẹ mẹjọ ti ade iwa ibajẹ si mọ lori kuro lẹnu iṣẹ.
Bakan naa ni wọn ni pe ki ọga agba Chief Superitendent of immigration lọ bẹrẹ isinmi kanpa lati fẹyin ti kuro lẹnu iṣẹ nigba ti wọn si din oye awọn mesan an mii ku.
Won si kede pe awọn oṣiṣẹ mẹfa lara awọn ti wọn fẹsun kan tẹlẹ wẹ, wọn yan kainkain.
Ninu atẹjade naa ni adari ileeṣẹ ijọba apapọ naa si ti fohun ranṣẹ pe ko si aaye fun iwa ibajẹ lọwọ awọn oṣiṣẹ rara.
O tun gba awọn ara ilu nimọran lati wa fi ẹjọ ẹnikẹni ti wọn ba kẹfin pe o n huwa ko tọ laarin awọn osiṣẹ wọn sun laibẹru