Àwọn ilé, ilẹ̀ Ike Ekweremadu tó lé ní 40 tí EFCC gbà tí wọ́n fẹ́ tà rèé...

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lorilẹede Naijiria, EFCC ti safihan awọn ile ati ilẹ to jẹ ti igbakeji aarẹ ile igbimọ aṣofin tẹlẹ, Ike Ekweremadu ti wọn gbẹṣẹ le.

Ajọ EFCC lo gbe igbeṣẹ yii lẹyin ti wọn gba aṣẹ ni ileẹjọ lati fi awọn ohun ini wọnyii lede fun awọn eniyan ti wọn ba ni ifẹ si lati saa.

Ajọ EFCC ni awọn bẹrẹ si ni sẹwadii Ekeremadu lẹyin ti awọn ikọ ọtẹlẹmuyẹ lati oke okun pe akiyesi wọn si ẹsun jẹgudujẹra ti wọn fi kan igbakeji adari ile igbimọ aṣofin agba tẹlẹri naa.

Ohun ti adajọ sọ ree...

Adajọ Agba Inyang Ekwo lo buwọlu igbẹṣẹ naa lẹyin ti EFCC bere aṣẹ lọwọ ileẹjọ lati gbeṣẹ le awọn ohun ini ti wọn fi ẹsun kan pe o ṣeeṣe ko kojo lasiko to lu owo ilu ni ponpo.

Bakan naa ni ajọ EFCC ni awọn gbẹṣẹ le awọn ohun ini wọnyii ki wọn ma ba ba wọn jẹ lasiko ti iwadii nlọ lọwọ.

Ileẹjọ wa paṣẹ pe ki wọn fi awọn ohun ini yii si inu iwe iroyin laarin ọjọ meje ti wọn gba aṣẹ ileẹjọ naa.

Bakan naa ni ileẹjọ paṣẹ pe awọn to ba ni ifẹ si awọn ohun ini yii ki wọn yọju lati jiroro lori idi ti ijọba ko fi ni gbẹṣẹ le patapata.

Adajọ ti sun igbẹjọ naa si Ọjọ Karun un, Oṣu Kejila, ọdun 2022 fun ẹkunrẹrẹ lori igbẹjọ naa.

Awọn ohun ini ti wọn fẹsun kan Ike Ikrewemadu pe o fi owo ilu to lu ni ponpo kojọ ree...

  • Ile nla ni ilu London ni agbegbe Flat 4, Varsity Court, Hormer Street ( WIH4NW) ti IkE Ekeremadu ra ni December 4, 2008 ni iye owo toto £830,000
  • Ile nla mẹta ni ilu Florida, lorilẹede Amerika ( o ra ọkan ninu wọn fun $155,000 USD; ti iwọn ilẹ naa to 3000 square meter to si ni yara meje, Boys Quarters, swimming pool, garagi igbe ọkọ si mẹta ati bẹẹ bẹẹ lọ)
  • Ile nla ni agbegbe No.6 Ilado Close, Ikoyi, ni ilu Eko to ra ni iye N630million ni Oṣu kẹjọ, ọdun 2015.
  • Ni ilu Abuja, ile alaja mẹfa ni ọna mẹta to ni fulaati mejidinlogun, ni agbegbe Plot 904 Durumi, Abuja, to ra ni iye toto N700million.
  • Bakan naa ni ile mẹrin (Four Rootown House) wa ni agbegbe Villa No. 148 Maeeni, ni Lahes Emirate Hill, ni orilẹede Dubai, ti iye rẹ si to $250,00 USD.