You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Japan: Ìjọba kéde pé àwọn ọ̀dọ́ kò tíì mu ọtí tó àwọn babańlá wọn
Ọ̀rọ̀ buruku, tòun ti ẹrin ni iroyin to jade ni orilẹede Japan yii.
Iroyin to jade lati orilẹede naa lo ni Japan fẹ ki awòn ọdọ wọn maa mu ọti si, ki idagbasoke le ba eto ọrọ aje wọn.
Awọn ọdọ Japan ni wọn ni wọn ko mu ọti to bi awọn agbaagba wọn se n mu ọti, idi si ree ti adinku fi ba owo to n wọle gẹgẹ bi owo ori ni Japan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ileeṣẹ ijoba apapọ Japan, to n gba owo ori wọle sọ pe, fun idi eyi ni won ṣe fi kun owo ori ọti bayii.
Bakan naa ni wọn sọ pe ileesẹ naa ti n woye ọna abayọ ti wọn yoo si fi maa jẹ ki awọn eeyan to pọ sii maa mu ọti.
Wọn ni pe awọn ọdọ asiko yii ni Japan ko mu ọti to awọn baba nla wọn, ni owo ko ṣe wọle pupọ lori ọti.
Kin ni ileeṣẹ to n mojuto ọrọ owo ori Japan ṣe yatọ?
Ileeṣẹ to n gba owo ori wọle ni Japan ti kede idije pe ki awọn ọlọpọlọ pipe ronu ọna abayọ ti awọn yoo fi se alekun owo to n wọle si orilẹede naa.
Eyi lo wa mu ki wọn bẹrẹ eto ipolongo idije "Sake Viva" ti yoo waye laarin awon eniyan ti ọjọ ori wọn wa láàrin ogun ọdun si ọdun mọkandinlogoji.
Afojusun ipolongo yii si ni lati mu ki wọn dije lori awọn nkan to maa jẹ ki ọti mimu wu awọn ọdọ bii ti wọn sii.
Ati pe wọn woye pe lati igba ti arun asekupani Covid 19 ti waye, ni ọrọ naa ti wọ wa, ti owo to n wọle.
Ileesẹ ijọba naa lo n fẹ ki awọn oludije mu ero ati ipolowo orisirisii to maa jẹ ki iyatọ wa.
Kin ni ero awọn ara Japan lori idije yii?
Bi awọn eeyan kan lorilẹede Japan se n sọ pe idije naa dara ni awọn mii ni pe o ku diẹ kaato lawujọ.
Bẹ́ẹ̀ náa ni awọn mii ti n sin wọn ni gbẹrẹ ipakọ lori ayelujara pẹlu apẹẹrẹ awọn nnkan ti wọn le ṣe lati mu ki owo to n wọle sapo orilẹede naa ru gọgọ si.
- Wo àwọn nọ́mbà ìpè agbófinró tó yẹ kò mọ̀, èyí tó pè tí ìkọlù agbébọn bá dé
- 'Láti ojú orun, ohùn kan máa ń tọ́ka ewé àti ègbòogi sí mi, báyìí la ṣe ń ṣe agbo fún ǹkan ọmọ ọkùnrin'
- Èèmọ̀ rèé o, Dókítà yọ eyín 526 lẹ́nu ọmọ ọdún méje
- Wo ohun mẹ́rin tó lè mú ikú wá lásìkò ìbálòpọ̀
- Ẹ wo bí ‘dókítà’ ṣe yọ àpò ẹyin ilé ọmọdébìnrin kan lásìkò iṣẹ́ abẹ́
Idije yii yoo wa sopin ni osu to n bọ, ninu eyi ti awọn to ba jawe olubori yoo kopa ninu aṣekagba idije losu kọkanla ọdun yii.
Iwadii fihan pe awọn eniyan ile Japan mu ọti lọdun 1995 ju ọdun 2020 lọ, eyi to jẹ lita ọgọrun un ni 1995 si lita marundinlọgọrin tọdun 2020.
Bakan naa ni wọn ni aimu ọti yii lo ṣakoba fun iye owo ori to n wọle eyi to jẹ ida marun ninu ọgọrun si ida kan o le diẹ ni 2020.
Ajọ Banki agbaye woye pe awon agbalagba ti ọjọ ori wọn bẹrẹ lati ọdun mọkandinlaadọrin soke to ida mokandinlọgbọn ninu ọgọrun un.
Yatọ si pe owo to n wọle dinku, ẹru ọjọ ọla awọn arugbo pẹlu itọju to yẹ si n ba awọn eniyan Japan.