China plane crash: Ọkọ̀ bàálù tó gbé èèyàn 133 já lórí àpáta Guangxi

Aririnajo mẹtalelọgọfa ati awọn ọmọ ẹgbẹ mẹsan wa lori ọkọ Boeing 737-800, ni Igbimọ Aabo ti Ilu China (CAA) sọ.

Iye awọn ti o farapa ati idi jamba naa ko tii di mimọ.

"A ti ran awọn oṣiṣẹ adoola lọ si agbegbe naa ati sọ pe ina kan ninu igbo ti o ṣẹlẹ nipasẹ jamba ọkọ ofurufu naa ti ku. Ibẹru wa pe ko si ẹnikan ti o ye ninu ọkọ ofurufu naa.

CAA sọ pe wọn tun ti ran oṣiṣẹ lọ si ibi isẹlẹ ọhun.

Orile-ede China ti ni ailewu oju ọna ofurufu ti o dara ni awọn ọdun mẹwa ti o ti kọja.

Awọn alaṣẹ China ko ti sọ ọrọ lori ijamba yii, tabi dahun si awọn ibeere, ṣugbọn lori ayelujara, o ti yi aami rẹ pada lori akọlẹ Weibo rẹ si awọ giree.

Ọkọ ofurufu MU5735 kuro ni Kunming ni ago kan kọja iṣẹju mọkanla - aago agbegbe (05:11 GMT) ti wọn ti ṣeto lati de Guangzhou ni ago mẹta kọja iṣẹju marun-un 15:05.

Awọn aaye ipasẹ ọkọ ofurufu fihan pe ọkọ ofurufu naa wa ninu afẹfẹ fun wakati kan, ati pe o ti sunmọ opin irinajo rẹ nigbati o jabọ ni Wuzhou.

Gẹgẹ bi FlightRadar24 data to n jẹ, alaye orisun ti o kẹhin lori ọkọ ofurufu naa fihan pe o pari ni ago meji kọja iṣẹju mejilelogun - akoko agbegbe naa, ni iwọn giga bata ẹsẹ ti 3,225 ft.

Ijamba ọkọ ofurufu nla ti o sele keyin ni orilẹ-ede naa ni ninu Oṣu Kẹjọ ọdun 2010, nigbati ọkọ ofurufu lati Harbin kọlu ni Yichun ti o pa eniyan mejilelogoji .