Storm Eunice: Àwọn aláṣẹ UK ti ṣèkìlọ̀ kónílé gbélé fún àwọn ènìyàn nítorí ìjì líle

Àwọn aláṣẹ ní orílẹ̀ èdè United Kingdom ti ṣèkìlọ̀ kónílé gbélé fún àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè náà bí ìjì líle, "Storm Eunice" ṣe ń ṣọṣẹ́ ní orílẹ̀ èdè náà.

Ìgbà kèjì rèé tí ilé iṣẹ́ Di Met ń ṣèkìlọ̀ lórí ìjì líle fún ìlú London, gúúsù ìlà oòrùn, ìlà oòrùn England, àwọn apá kan ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn England àti gúúsù Wales.

Ìkìlọ̀ yìí ni Di Met ní ó túmọ̀ sí pé àwọn nǹkan tí ìjì yìí le gbé le ṣe àkóbá fún àwọn ènìyàn.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ilé ẹ̀kọ́ ni wọ́n ti tì pa, gbogbo àwọn ọkọ̀ ojú irin ní Wales kò ṣiṣẹ́ mọ́ báyìí, tí àwọn ọmọ ogun náà sì ti wà ní sẹpẹ́.

Ẹ̀ka tó ń rí sí ìwòye ojú ọjọ́ BBC ní ó ṣeéṣe kó jẹ́ ìjì tí yóò burú júlọ fún UK láàárín ọgbọ̀n ọdún.

Ìjì Eunice ni ìjì líle kejì tó ń wáyé ní UK lẹ́yìn tí ìjì Dudley ṣọṣẹ́ ní àwọn apá kan Scotland, àríwá England àti àríwá Ireland, níbi tí ọ̀pọ̀ ènìyàn kò ti níná ní ilé mọ́.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Irú ìkìlọ̀ yìí sábà wáyé nítorí ó túmọ̀ sí pé òrùlé ilé le ṣí, òpó iná le wó, tí àwọn igi sì le hú.

Nínú oṣù kọkànlá ọdún tó kọjá ní irúfẹ́ ìkìlọ̀ báyìí fún ìjì Arwen ti wáyé.

Awòṣakun ojú ọjọ́ BBC, Ben Rich ní ìjì líle Eunice yóò fa wàhálà ṣùgbọ́n òun kò mọ bí ó ṣe le pọ̀ tó.

Derek Brockway ní ìjì Eunice kìí ṣe hurricane ṣùgbọ́n ó ṣeéṣe kí ọwọ́ rẹ̀ yóò bá ti hurricane.

Di Met ní kí àwọn ènìyàn ṣọ́ra fún rínrin ìrìnàjò.