Uttar Pradesh: Èèyàn mẹ́tàlá jáde láyé léyìn tó wọ́n já sínú kànga níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó

O kere tan, eeyan mẹtala ti dagbare faye lẹyin ti wọn ja sinu kanga nibi ayẹyẹ igbeyawo kan ni Uttar Pradesh to wa ni iha Ariwa orilẹ-ede India.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn to ba iṣẹlẹ laabi naa lọ, ti wọn jẹ ọmọde ati obinrin, joko sori pako kan ti wọn fi bo ori kanga naa.

Amọ irin naa ja, awọn eeyan ọhun si jabọ sinu kanga naa.

Yatọ si awọn mẹtala yii, eeyan meji mii tun farapa nibi iṣẹlẹ ọhun.

Olootu ijọba ilẹ naa, Narendra Modi ti juwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bii eyii to ba oun lọkan jẹ gidi.

Ọjọru ni iṣẹlẹ naa waye lasiko ti eto igbeyawo "haldi" naa n lọ lọwọ, nibi ti awọn ẹbi ti kun nnkan si oju tọkọ-tiyawo lọna ati fi sami si igbeyawo ọhun pe yoo yọri si rere.

Ni kete ti pako ti awọn eeyan naa joko le lori ja, awọn eeyan to wa nibi ayẹyẹ igbeyawo naa ṣu bo wọn lati doola wọn.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe eeyan mọkanla lo ku lẹsẹkẹsẹ, nigba ti awọn meji toku jade laye nibi ti wọn ti n tọju wọn.

Olootu ijọba Yogi Adityanath ti ke si awọn adari ipinlẹ ti iṣẹlẹ na ti waye lati dide iranlọwọ fun mọlẹbi awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ.