NUC Rankings 2021: Púpọ̀ nínú àwọn Fásìtì tó ń gbà owó gọbọi lọ́wọ́ akẹ́kọ̀ọ́ ló fìdí rẹmi nínú ìgbéléwọ̀n wà- NUC

Ninu gbogbo fasiti to wa ni Naijiria,marundinlọgbọn pere ni a ti fòntẹ̀ lu awọn eto ẹkọ tí wọn n se fawọn akẹkoo.

Ohun tí àjọ tó n mojuto eto awọn ile ẹkọ Fasiti Naijiria so di mimọ ree pẹlu igbelewọn ọdun 2021 to se fawọn ile ẹkọ gíga ilẹ naa.

Bẹẹ ni ajọ na fi kun pe awọn eto ẹkọ tàwọn fòntẹ̀ lù láwọn fasiti to ku ko to ida aadọrin ninu ida ọgọrun un.

Mẹjọ ninu awọn fasiti ọgọrun le mẹtala tawon àjọ yi se ayẹwo gẹgẹ bí ile iṣẹ iroyin Naijiria The Nation se so ni won6 ko fọwọ́ sí wòrò kan ninu awọn eto eko5 ti wọn n ṣe.

Ninu wọn lati ri "Nigeria Army University, Biu, ni ipinlẹ Borno State ati Air Force Institute of Technology.

Lapapọ fasiti 170 ti ijoba ati aladani lo wa ni Naijiria.

Gẹgẹ bí àjọ NUC ti ṣe sọ ko kankan ninu awọn fasiti 113 tàwọn yẹ wò ti iye ọjọgbọn tó yẹ ki wọn ni pé perepere.

Ninu àtẹ igbelewọn ti ajọ yi ṣe fawọn fasiti bakan náà yunifasiti Ibadan UI lo sọ pe o le tente pẹlu ami 454.5

Fasiti aladani Redeemers University lo n tọ lẹhin pẹlu ami 384.96 ;

Covenant University (368.11 points);

Ladoke Akintoka University, Ogbomoso (315.23 points) ati

Federal University of Technology Akure (264.14 points).

O jẹ iyalẹnu pe ko sí kankan ninu awọn fasiti wọnyi ti orukọ wọn jáde nínú fasiti marundinlọgbọn ti wọn fòntẹ̀ lù gbogbo eto ẹkọ pe o kaju osunwọn eleyii táa mọ sí pé wọn gba "accreditation" lede Gẹẹsi.

Awọn fasiti marundinlọgbọn to wẹ gan kankan nípa gbígbà accreditation yi ni awọn fasiti wọnyi:

Adeleke University, Osun State;

Al-Qalam University, Katsina

Caleb University, Lagos

Chrisland University, Lagos

Crescent University, Ogun

Federal University, Lokoja,

Federal University, Wukari,

Federal University, Kashere.

Ninu wọn la tun ti ri :

Hallmark University, Ogun

Hezekiah University, Imo

 Ibrahim Babangida University, Niger

Igbenedion University, Edo

Kano University of Science and Technology, Kano;

Kebbi State University of Science and Technology,

Kogi State University ati

Maitama Sule University, Kano

Awọn to ku ni:

McPherson University, Ogun

Mountain Top University, Ogun

Niger Delta University, Delta

Nigeria Defence Academy;

PAMO University of Medical Science, River

Rivers State University;

Samuel Adegboyega University, Edo

Summit University, Kwara ati

Umaru Musa Yar'Ardua University, Katsina

Àjọ NUC salaye ninu abajade iwadii wọn pe awon akoṣẹmọṣẹ lati ẹka eto awọn fasiti mokanlelaadorin lo se iwadii yi.

Ọgá agba àjọ yi teleri Ọjọgbọn Peter Okebukola lo darí ìkọ naa.

Wọn tẹsiwaju ninu abajade wọn pe púpò awọn fasiti to n gba owó gọbọi lọwọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lo fìdí rẹmi ninu igbelewọn náà.