You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
INEC 2023 Election: Èrò àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí N305 bílíọ̀nù náírà tí INEC fẹ́ ná fi ṣètò ìdìbò 2023
Ajọ to n mojuto eto idibo lorileede Naijiria INEC ti ṣe agbekalẹ owó ìṣúná marunlelọọdunrun biliọnu naira niwaju ile aṣofin Naijiria.
Ninu alaye ti wọn ṣe,wọn ni awọn nilo owo yi lati le fi ṣètò idibo ti ko ni lọwọ magomago ninu.
Wọn fikun ọrọ wọn pe owo yi yatọ sí owó ogoji mílíọ̀nù naira tàwọn ma fi n ṣe owo ìṣúná ọlọdọọdun àjọ náà.
Lati igba ti wọn ti kéde ọrọ yi ni awọn ọmọ Naijiria kan ti n beere pe kini wọnyi fẹ fi aduru owo yi se.
- Wo orílẹ́èdè tó fẹ́ fi òfin de sìgá mímú fún ìran ọmọ wọn tó ń bọ̀
- Èmi ò ṣetán láti gbẹ̀mí ara mi o, ohun tó ṣẹ̀lẹ̀ ni pé...- Ibrahim Chatta
- Wo bí olórí ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tẹ́lẹ̀, Gabriel Boric, ẹni ọdún 35 ṣe wọlé ìbò ààrẹ Chile
- Èrò àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí N305 bílíọ̀nù náírà tí INEC fẹ́ ná fi ṣètò ìdìbò 2023
- Tinubu, fi ipò ààrẹ sílẹ̀ fáwọn ọ̀dọ́ lọ́dún 2023- Osita Okechukwu
Kini INEC ni pe won fẹ fi owo yii ṣe ni pato?
Alaga ajọ naa Ọjọgbọn Mahmood Yakubu to se agbekalẹ aba owo yi níwájú igbimọ ile to n risi owo nina lọjọ Aje sọ pé wọn ti fún àjọ náà ni ọgọrùn un bílíọ̀nù naira ninu owo yi ṣugbọn ko ni to lati fi ṣe gbogbo nkan ti wọn fẹ ṣe nigbaradi idibo 2023.
Gẹgẹ bo ti ṣe sọ, o ni INEC ti fi aba ìṣúná yi ṣowọ gba ọdọ igbimọ alaṣẹ pé kí wọn fi kun ìṣúná wọn níwájú ilé aṣòfin Nàìjíríà eleyi ti wọn fẹ buwọ́lù ni ọjọ Isẹgun.
" A f'ara balẹ gbe aba ìṣúná marunlelọọdunrun biliọnu naira yi kalẹ ni pẹlu ẹkunrẹrẹ alaye lori re"
O fi kun ọrọ rẹ pe ninu aba náà wọn pèsè mílíọ̀nù ogoje fún INEC "eleyi la sí ṣe atupalẹ rẹ níwájú igbimọ ile mejeeji"
"Ogoje mílíọ̀nù Náírà yi a pin sí Meji.
ogoji biliọnu ninu re la fi ṣe ìṣúná ọlọdọọdun wa ti eleyi to ku,ọgọrun biliọnu, si jẹ ipele akọkọ táa fi ṣètò idibo 2023 táa rí gba"
O tubọ ṣe alaye pe ninu nkan tàwọn ṣe iṣiro kale pe àwọn yóò lo owo yi fún ni owo iṣeto awọn idibo paapa awon eyi ti ko bọ sí akoko idibo ti gbogbo eeyan mọ.
"Ohun tí a fẹ kí igbimọ yi mọ ni pé a ní idibo atundi mẹjo to wa nilẹ.
Mẹta je ti ẹkun idibo apapọ t'awọn marun un sì jẹ ti ẹkun idibo ipinlẹ.Koda aaye idibo to ṣi silẹ ṣẹṣẹ waye lọjọru to koja yi ni nigba ti ọmọ aṣoju ile ẹkun Jiwa West ni ipinlẹ Kaduna papoda"
Ki ile bàa lè gbọ alaye to se daadaa lori ipe wọn sì ilé láti jọwọ diẹ ninu biliọnu N205 to sẹku,
Ọjọgbọn Yakubu ka awọn eto tàwọn fẹ fi owo naa ṣe ṣaaju idibo 2023.
Ninu eto yi la ti ri ṣiṣe eto idibo abẹle fawọn ẹgbẹ oṣelu gẹgẹ bó ti ṣe àlàyé.
Alaga igbimo ile,Seneto Jibrin Barau nigba to n fesi sọ pe awọn yóò rí pe INEC ri owó tó nilo gba ninu aba ìṣúná ọdún 2022 lati le fi ṣètò idibo.