Bola Tinubu, Osita Okechukwu: Ọ̀gá àgbà ilé-iṣẹ́ ìròyìn VON rọ Tinubu láti gbárùkù ti ọ̀dọ́ olùdíje fún ipò ààrẹ lọ́dún 2023

Ọga agba ileeṣẹ iroyin VON, Osita Okechukwu ti rọ Aṣiwaju Bola Tinubu lati ṣe atilẹyin fun ọdọ oludije fun ipo ààre lati apa guusu orilẹ ede Naijiria.

Okechukwu to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC lati ibẹrẹ sọrọ yii fawọn akọroyin niluu Abuja lọjọ Aiku.

"Bi ẹnìkan bá bi mi leere pe ki n fun Tinubu ni imọran, ohun ti mo maa sọ fun un ni pe ki o lo gbogbo agbara rẹ ti Eledua jogun fun un lati wa iṣọkan ẹgbẹ oṣelu APC.

Ati pe ki o lo gbogbo agbara rẹ lati gbaruku ti ọdọ oludije kan lati apa guusu Naijiria ninu eto idibo ọdun 2023," ọga VON lo sọ bẹẹ.

Ọgbẹni Okechukwu ni atilẹyin lo yẹ ki Tinubu ṣe fun ọdọ oludije fun ipo ààrẹ papaa julọ oludije lati ilẹ Ibo.

Okechukwu ni ọna yii lo le mu Tinubu so ẹkun guusu pọ pẹlu bi awọn oloselu Oke Oya ṣe sọ pe aifẹnuko ilẹ Yoruba ati Ibo lo dáwọn lọwọ kọ lati ṣe atilẹyin fun oludije ipo ààrẹ lati apa guusu.

Ọga agba VON ni ti Tinubu ba foju silẹ daadaa, yoo ri oludije ọdọ to dara nilẹ Ibo ti o le ṣe atilẹyin fun lati la Atiku Abubakar ẹgbẹ oṣelu PDP mọlẹ ninu ibo ààrẹ ọdun 2023.

Okechukwu ni o dara ki Tinubu maa ṣe afọbajẹ ju ki oun fún ra rẹ dupo ninu ibo aarẹ lọ.

"Iwe mímọ gan an sọ pe gbogbo nkan ni akoko ati igba wa fun lorilẹ aye.

Mo jẹ ọkan lára àwọn ọmọlẹyìn Buhari ti ko le ko iyan Tinubu kere papaa julọ fun iṣẹ ribi ribi to ṣe ti Buhari fi ri ibo miliọnu mejila ninu ibo aarẹ ọdun 2015.

Amọ, asiko ti to fun Tinubu lati ṣe atilẹyin fun ọdọ oludije ninu ibo aarẹ,"Okechukwu lo sọ bẹẹ.

Laipẹ yii ni Tinubu sọ pe oun ṣetan da awọn ololufẹ oun to n rọ oun lati dupo aarẹ ninu ibo gbogboogbo ọdun 2023.