Iyabo Oko's illness: Nítòótọ́ ni ìyá wa kò lè ṣe tíátà mọ́ ṣùgbọ́n a ń tọjú rẹ̀ pẹ̀lú ìwọ̀nba tí agbára wa ká- Ewa

Eyi lo mu awọn ọmọ lọkan ti wọn fi ko owo ti kii ṣe kekere rara jọ lati gbee lọ si Orileede India.

Erongba ọkan wa ni pe ara rẹ yoo ya tori awọn dokita ni arun rọpa rọsẹ ti oni igba diẹ ni to si lo bii ọdun kan lọhun ko to pada wale.

Lati igba to ti de ni Ewa ni oun ati ẹgbọn oun naa lawọn n fi owo ranṣẹ́ sii fun itọju ara rẹ tori ko lee ṣe iṣẹ tiata ọhun mọ tori ara ko fibẹẹ ṣe daadaa.

Kò sóhun tó ṣe Iyabo Oko, Ọlọ́run kò ní jẹ́ kí máàmi kú báyìí - Ọmọ Iyabo Oko bú sẹ́kún.

Ọmọ bibi gbajugbaja agba oṣere to wa lori akete aisan nla lọwọ, Iyabo Oko ti jade wa sọ fesi si iroyin iku ti awọn eeyan n gbe kiri nipa agba oṣerebinrin naa.

'Màmá mi, Iyabo Oko ti ní "Left Stroke" ní fọ́tò wọ́n ṣe rí bẹ́ yẹn o àmọ́...'

Oduola Olamide to jẹ abigbẹyin Iyabo Oko ni oun deede gba ipe ni ile iwosan nibi ti oun ti n duro ti iya oun pe wọn ni o ti ku.

Olamide ba bẹ̀rẹ̀ si ni ta ika aburu sẹyin pe lagbara Ọlọ̀run iya oun ko ni ku, nkankan ko si ni ṣee.

O ni oun gbọ pe wọn ni ọmọ ti Iyabo Oko bi fun agba oṣerekunrin Koledowo lo gbe iroyin naa jade pe Iyabo Oko ti ku amọ Olamide ni oun yii kan naa ni ọmọ kan ṣoṣo ti Iyabo Oko bi fun Koledowo.

Ati pe oun ko si gbe iroyin ibi kankan sita toripe oun loun wa lọdọ mama awọn.Báyìí ni ìrìnàjò àìsàn Iyabo Oko ṣe bẹ̀rẹ̀ láti ọdún márùn ún ṣẹ́yìn

Nigba ti BBC Yoruba kan si ọkan lara awọn ọmọ Iyabo Oko to dagba, arabinrin Ewa Adegoke ni lati bii ọdun marun un to ti rẹ mama awọn naa lo ti maa n lo ogun rẹ lẹyin ti awọn gbe e lọ si ile iwosan ti dokita ni arun rọpa rọsẹ apa osi lo n daa laamu.

Ọmọ bú sẹ́kún pé kí ẹnikẹ́ni má ro ikú ro ìyá òun

Iyabo Oko jẹ eeyan to gbajumọ nigboro tori iṣẹ rẹ amọ ọmọ rẹ sọ fun BBC Yoruba pe nigba ti awọn ti na ọpọlọpọ owo, iya awọn to n wa ọkọ tẹlẹ wa di ẹni to n gun ọkada nigboro tawọn eeyan si n rii.

O ni awọn tiraka lati kọ ile fun un n'Ibadan awọn si pada wa ọkọ mii ra fun un.

Ẹwa ni bii ọjọ melo kan sẹyin ni igba mii, wọn a sọ fun awọn pe mama awọn dede ṣubu lori ọkada pe wọn tun ti gbee digba digba lọ ile iwosan. Eyi ni gbajugba ja oṣere yii n ba finra fun ọpọ ọdun ko to tun wa wọọ lara ni nkan bii ọjọ diẹ sẹyin ti aburo awọn pe awọn pe aisan tun ti kọ lu u tori naa ko le ṣe nkankan, ko si le dide mọ.

Wọ́n ti wa gbee lọ si ile iwosan bayii ti awọn dokita sọ pe ai kii wa si ile iwosan dede fun ayẹwo lo da kun nkan to ṣee bayii ti rọpa rọsẹ apa osi yẹn ti wa di tootọ bayii to ti di ti eyi ti mama Iyabo Oko ko lee ṣe nkankan mọ.

Gẹgẹ bi aburo mi ṣe sọ fun mi o ni "mama ti n kọminu nipa ipo to wa lọwọlọwọ yii, ẹ mọ ẹni to ti n wa mọto kiri tẹlẹ to n gbe igbesi aye gidi to wa di pe o n gbe ọkada kiri Ibadan, awọn eeyan ma maa beere ni pe ki lo ṣẹlẹ eyi n ti wọn loju".

Lori ipo ti mama wa lọwọlọwọ yii, Ewa sọ fun BBC Yoruba pe "mama ti ni "Stroke" ni ọwọ ati ẹsẹ osi bayii ti wọn ko le yi ọrun si ẹgbẹ mọ". O ni eyi lo faa ti awọn eeyan n ri wọn ninu fọto ti wọn fi n sọ oriṣiriṣi.

"Mama o ku o, wọn ṣi wa laye daadaa. Koda wọn ṣi gbadura lana fun gbogbo awọn to n nawọn iranwọ fun wọn".