You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
School Children Kidnap: Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọlé padà fún sáà ọdún 2021/2022, kíni ìrètì àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wà ní àhámọ̀ ajínigbé?
Ni asiko yii ti awọn akẹkọọ ti wọle ileẹ̀kọ́ pada ni ọkan awọn Obi ti n poruru lori eto aabo awọn ọmọ wọn.
Koko meje yii yoo wulọ fun awa Obi:
Rii aridaju pe awọn ọmọ rẹ tete n wọle sun lasiko, nitori pe a tete sun ni a tete ji.
Ma ṣe kọ orukọ awọn ọmọ rẹ si ara baagi tabi aṣọ wọn lọna ti o maa hande si ara ita.
- Ẹ̀yin oníṣègùn ìbílẹ̀, ẹ bá wa ṣe àwárí oògùn àjákálẹ̀ àrùn covid-19- Ìjọba Naijiria
- Àwọn jàndùkú jí Emir Bungudu gbé, wan pa ọlọ́pàá lọ́nà mọ́rosẹ̀ Abuja sí Kaduna
- Lóòtọ́ ni ìyá yìí bímọ méjì fún ọmọ rẹ̀ tó ń bá sùn, ohun tí a ṣe síi rèé - Àjọ NSCDC Kwara
- Atọ́kùn egúngún, ọmọ rẹ̀ àti èèyàn méjì dèrò àtìmọ́lè lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn ní mọ́ṣálááṣí
- Ìwọ́de Yoruba Nation lólú iléeṣẹ́ àjọ UN wáyé, bó ṣe lọ nìyí
Ba awọn ọmọ rẹ sọrọ ni kikun lori ipenija eto aabo to n lọ lọwọ ni Naijiria ki awọn naa le tun maa ṣọra.
Gbiyanju lati ra awọn nkan ti ọmọ rẹ maa nilo ki wọn maa baa fi tan an lọ.
Kilọ fun ọmọ rẹ lati ma se ba ẹnikẹni ti ko mọ ri sọrọ loju ọna to ba n lọ sile ẹkọ rẹ.
Wo ọna ti awọn ọmọ rẹ a maa gba lọ sile ẹkọ ati lati pada wa sile, rii pe o mọ onimọto tabi ọlọkada tabi awọn ti ọmọ rẹ jọ n lọ sile ti wọn si jọ n bọ.
Mọ sii nipa awọn to n yọ ọmọ rẹ lẹnu ni kilaasi bii ẹni to ba n huwa agbaaya sii.
Ṣiṣẹ lori ibi ti o ba fé fi ọmọ rẹ si lẹyin to ba ṣetan nile ẹkọ.
Mojuto ọrọ eto ilera ọmọ rẹ lasiko.
'Ó lé ni akẹ́kọ̀ọ́ 1,000 tí àwọn ajínigbé kó láàrin oṣù kíni sí ìkẹjọ 2021'
Awọn onimọ nipa eto ẹkọ awọn ogo wẹẹrẹ lagbaye, Ajọ Unicef ti fi aidunnu wọn han si bi awọn akẹkọọ ko ṣe tii gba itusilẹ ni ahamọ awọn ajinigbe kaakiri orilẹede Naijiria.
Eyi ko ṣẹyin bi awọn akẹkọọ ṣe wọle pada ni Ọjọ Aje, Ọjọ Kẹtala, Oṣu Kẹsan an, ọdun 2021 fun saa ọdun 2021/2022.
Ẹgbẹgbẹrun awọn akẹkọọ kaakiri orilẹede Naijiria ni yoo pada si ileewe fun eto ẹkọ, amọ ọrọ ko ri bẹẹ fun awọn to wa ni iha ariwa orilẹede Naijiria nibi ti wọn ti n ji awọn akẹkọọ gbe lọgọọrọ.
- Báyìí ni ìrìnàjò àìsàn Iyabo Oko ṣe bẹ̀rẹ̀ láti ọdún márùn ún ṣẹ́yìn
- Wo ìdí tí àwọn obìnrin kan fi n yọ ilé ọmọ wọn kúrò
- Ọwọ́ ti tẹ ọlọ́pàá tó yìnbọn pa ọmọ ọdún 18 nílùú Eko
- Ìjọba àpapọ̀ sọ̀rọ̀ lórí bí ọmọ ilẹ̀ Italy ṣe pa ìyàwó rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ Naijiria
- Wo iye kọ́ńdọ́mù táwọn ọmọ Nàìjíríà fi ń ṣara rindin lọ́dún
Ajọ UNICEF ninu iwadii ti wọn fi lede pe o kere tan awọn akẹkọo to le ni ẹgbẹrun ni awọn ajinigbe ti jigbe ni ileẹkọ wọn laarin oṣu mẹjọ ninu ọdun 2021.
Bakan naa ni iwadii fikun pe o kere tan awọn akẹkọọ to le ni ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta ni ko ni anfaani si eto ẹkọ to ye kooro mọ lati ọdun 2018.
- Bí ọwọ́ wa kò bá tẹ àwọn tó lọ́wọ́ nínú ìkọlù sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Kabba, a kò ní sinmi- Aregbesola
- Kókó nǹkan tí ẹgbẹ́ NINAS ń bèrè fún ní ibi ìpàdé UN General Assembly
- Wo iye àwọn tó ti gbẹ̀mí ara wọn ní Nàìjíríà láàrin ọdún mẹ́rin ìjọba Buhari
- Femi Ojudu faṣọ iyí mọ́ Kayode Fayemi lára, Ó ní ojú ń gba òun ti fún ipò táwọn títì Ekiti wà
- Wo ọ̀nà méje tí o lè fi dáàbò bò ọmọ rẹ níbàyìí tí iléẹ̀ka ti bẹ̀rẹ̀ padà
Eyi ti ko ṣẹyin ijinigbe ojoojumọ to n waye ni awọn agbegbe naa.
Awọn ẹgbẹ ajafẹtọ ọmọde, Save the Children International naa rọ ijọba Naijiria lati ṣe eto aabo to muna doko fun awọn akẹkọọ ni awọn ileẹkọ won.
Ajọ naa ni titi di asiko yii, ọpọlọpọ akẹkọọ lọ ṣi wa ni panpẹ awọn ajinigbe nibi ti wọn ti n bere owo ẹmi wọn.
O kere tan ọgọrun ileẹkọ ni awọn agbebọn ti ṣe ikọlu si kaakiri orilẹede Naijiria laarin ọdun 2019 si 2021, eleyii to ti mu ki awọn ọmọde yẹra fun ileẹkọ lọna ati doola ẹmi wọn.
Bakan naa ni Ajọ ẹṣọ alaabo ni Naijiria, NSCDC ni o kere tan ida marundinlaadọrun awọn ileẹkọ ni Naijiria ni ko si aabo to peye fun, paapaa ni awọn agbegbe bii Kaduna, Katsina, Kebbi, Zamfara ati Niger.
Laipẹ yii ni awọn ajinigbe ko awọn akẹkọọ to le ni aadọrin ni ileẹkọ Government Day Secondary School, Kaya, ni ipinlẹ Zamfara.
- Ọmọ Naijiria tó ń ṣe Yahoo rí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ̀rin he l'Amẹrika
- Wo díẹ̀ lára bí wọ́n ṣe sàmì ìrántì ìkọlù 9/11 ní America
- Kí ló lè mú ẹni ọdún mẹ́tàlélógún tó wà ní ND2 yìí pokùnso?
- Wo ìdí tí àwọn obìnrin kan fi n yọ ilé ọmọ wọn kúrò
- Ẹ dákun ẹ ran Iyabo Oko lọ́wọ́, ìyá ti ń ṣàárẹ̀ láti ọdún márùn ún sẹ́yìn, o ti kọjá agbára wa- Foluke Daramola Salako
Lẹyin ti awọn akẹkọọ ileẹkọ Tanko Salihu Islamic School ni Tegina, ni ipinlẹ Niger, to fere to ẹgbẹrun gba itusilẹ lẹyin oṣu mẹta ti wọn ti wa ni panpẹ awọn ajinigbe.
Ajọ ọmọlẹyin Kristi, CAN ti ipinlẹ Kaduna wa kesi ijọba lati doola ẹmi awọn akẹkọọ mọkanlelọgbọn ti ileẹkọe Bethel Baptist High School, Damishi, nipinlẹ Kaduna, ti wọn ṣi wa ni panpẹ awọn ajinigbe.
Ajọ CAN fi ẹsun kan ijọba apapọ wi pe wọn ko naa ni ẹmi awọn ọmọ naa ni wọn ṣe fi wọn silẹ ni inu igbo, lai bikita boya awọn ajinigbe naa ti fi ẹmi awọn ọmọ naa ṣofo.
Nibayii, awọn ẹlẹṣọ aabo, onimọ nipa eto ẹkọ to fi mọ awọn ẹka ijọba lorisirisi n pe fun atunṣe awọn ileẹkọ, paapaa ogiri to ga soke ati awọn ohun elo ẹṣọ alaabo miran fun awọn ileewe wọnyii, lọna ati doola ẹmi awọn akẹkọọ lasiko ti wọn ba wa ni ileẹkọ.