Rufus Giwa Polytechnic murder: Kí ló ṣẹlẹ̀ sí akẹ̀kọ̀ọ́ tí wọ́n ṣá pa?

Rukerudo waye ni ileewe giga Rufus Giwa Polytechnic ni ilu Ọwọ, nipinlẹ Ondo, lẹyin ti iroyin kan pe wọn ṣa akẹkọọ ni ada pa.

Alukoro ileewe Rufus Giwa Polytechnic, Samuel Ojo fi idi ọrọ naa mulẹ pe lootọ ni iṣẹlẹ naa waye.

Arakunrin Ojo ni iwadii ṣi n lọ lori ohun to ṣekupa ọmọ ileewe naa.

O ni lọọto ni iṣẹlẹ naa waye ni asiko ti wọn ṣe idibo fun awọn asoju awọn akẹkọọ ni ileewe naa.

Alukoro ileewe naa ni oun ko lee fi idi rẹ mulẹ pe idibo naa niiṣe pẹlu iṣekupani naa, nitori ko si aridaju iṣẹlẹ ọhun.

Amọ, iroyin miran gbe e pe awọn ẹlẹgbẹ okunkun to doju kọ ara wọn lo ṣekupa akẹkọọ naa.

Bakan naa ni iroyin naa ni wọn sa akẹkọọ naa pa nitori awọn ikọ rẹ lo wọle ninu idibo sipo asoju ileewe naa.

Amọ, ileeṣe ọlọpaa ni ipinlẹ naa ni awọn ko i tii le fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ titi di asiko yii.

Bakan naa ni ileewe naa ko i tii fi atẹjade sita lori iṣẹlẹ naa ati esi idibo awọn akẹkọọ naa.