Àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Nàìjíríà dóòlà ẹ̀mí ẹni méjì ní Owena ní Ondo

Awọn ọmọ ogun Naijiria ti ẹka 32 Artillery Bridgade ni Bareke Owena ni Ondo ti doola ẹmi awọn eniyan meji lọwọ awọn ajinigbe.

Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ awọn ajinigbe lo gbe wọn lasiko ti wọn n rinrin ajo lẹnu oko owo wọn.

Lasiko to n fi idi bi wọn se ri wọn gba silẹ, igba keji adari ibaṣepo ara ilu fun ile ișẹ ọmọ ogun ni ipinlẹ Ondo, Ayorinde Omojokun, salaye fun awọn akọroyin pe awon ọmọ ogun se awari ibi ti awọn eniyan naa wa pẹlu iranlọwọ awọn ikọ IGP - IRT nínu igbo kan ni Iboropa.

Gẹgẹ bi o ṣe sọ, awọn mejeeji ti wọn ji gbe naa Aremọ Abiodun, ẹni aadọọta ọdun, ati abilekọ Agnes Afogun aadọta ọdun n rinrin ajo lọ si ilu Ugbe lọ Simerin fun okoowo nigba ti wọn ji wọn gbe.

O fi idi rẹ mulẹ pe ilu Ugbe Akoko ni awọn ti doola wọn.

Omojokun lorukọ awọn ọmọ ogun naa ṣalaye pe: "Awọn agbebọn naa ti beere ọgbọn miliọnu Naira lọwọ ọkọ abilekọ Afogun ki wọn to fi wọn silẹ.

Ẹwẹ, o fi kun un pe wọn san owo idasilẹ lọwọ awọn mejeeji ki wọn to gba itusilẹ, awakọ ati olokoowo ni awọn mejeeji.

Omojokun ni awọn gba ibọn ati ada lọwọ awọn ajinigbe lasiko ti wọn ṣe iṣẹ naa.