You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
2023 Election: Àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ ìlú kan kórajọ láti dá ẹgbẹ́ òṣelú tuntun sílẹ̀
Ajafẹtọ ọmọniyan, Femi Falana ti sọ pe kaka ki ewe agbọn dẹ, kokoko lo tun n le si i lọrọ awọn ẹgbẹ meji to ti n ṣejọba ilẹ Naijiria lati nnkan bi ogun ọdun sẹyin wa jẹ.Falana lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba.O ni ẹgbẹ tuntun ti oun atawọn kan gbe kalẹ, National Consultative Front, NCF, ti bẹrẹ apero lati wa ọna abayọ si iṣoro ti Naijiria n dojukọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ọ̀nà tí àwọn ‘ẹ̀lẹ̀ Daddy’ gbà dé ààfin Ọyọ
- Àlàyé rèé lórí ikú tó pa Adegbenro, Kọmísánà l‘Ondo
- Bí òṣìṣẹ́ tó ń ta epo nílé epo ṣe di onímọ̀ ìṣẹ́gun òyìnbó, kàyéèfì ńlá!
- Ṣé ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro Nàìjíríà ní ẹgbẹ́ òṣèlú tuntun ti Falana, Ezekwesili àtàwọn 28 mìí dá sílẹ̀ yìí?
- Ilé ẹjọ́ yẹ àga mọ́ Ọba Ìkirè nìdí lẹ́yìn ọdún 27 lórí ìtẹ́
- Ayédèrú Lọ́yà tó ń díbọ̀n gbowó lọ́wọ́ aráàlú bọ́ sí gbaga ọlọ́pàá
O ni ti wọn ba ti pari apero wọn tan, ẹgbẹ naa yoo jẹ ki awọn ara ilu mọ iyatọ to wa ninu ẹgbẹn tuntu naa atawọn ẹgbẹ to ti wa latẹyinwa.Falana tẹsiwaju pe "Awọn ọmọ Naijiria ti ṣetan lati tẹwọgba ẹgbẹ tuntun miran ti yoo mu aye dẹrun fun wọn.."O ni ijọba to wa lode báyìí ko kọbi ara si bi awọn ọdọ ko ṣe ri iṣẹ ṣe ati bi awọn eeyan ṣe n ku iku ọwọwọ nitori oniruru aisan to wa lodeNi ti eto idibo sipo aarẹ ti yoo waye lọdun 2023, Falana sọ pe ko si ẹgbẹ tuntun ti yoo jade ti ko ni fẹ du ipo oṣelu, ṣugbọn awọn ẹgbẹ to wa lode lọwọ yii ko kọbi ara si ẹdun ọkan awọn ara ilu.
National Consultative Front: Femi Falana, Oby Ezekwesili àtàwọn 28 mìí gbé ẹgbẹ́ òṣèlú tuntun kalẹ̀- 2023 Election
Ni igbaradi fun idibo gbogboogbo ti yoo waye lọdun 2023, awọn ajafẹtọ ọmọniyan ọgbọn, awọn ọmọwe atawọn eeyan miran ti parapọ gbe ẹgbẹ oṣelu tuntunkan kalẹ.
Orukọ ti wọn pe ẹgbẹ oṣelu tuntun naa ni National Consultative Front, NCF.
Wo diẹ ninu awọn to wa ninu ẹgbẹ oṣelu tuntun naa:
Lara awọn to wa ninu ẹgbẹ naa ni; Agbẹnusọ ile igbimọ asọju tẹle, Ghali Na'abba, igbakeji gomina banki apapọ Naijiria tẹlẹ, Obadiah Mailafia.
Awọn eeyan jankan miran to tun wa nibẹ ni, agbẹjọro agba Olisa Agbakoba ati Femi Falana, ajagunfẹyinti Abubakar Umar, sẹnatọ Shehu Sani ati ọmọwe Oby Ezekwesili.
Wọn ni asiko ti to ki ẹgbẹ oṣelu tuntun to ṣetan lati gbeija ara ilu dide giri lasiko yii yatọ si ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP to n paarọ aṣọ lara awọn oloṣelu.
Kini Afojusun ẹgbẹ oṣelu National Consultative Front:
Afojusun ẹgbẹ naa ni lati ko awọn ọmọ sọdi lati le kan an nipa fun ijọba lati ṣe awọn ofin ti yoo ṣe anfani fun gbogbo mutumuwa.
Bakan naa ni ẹgbẹ ọhun ni wọn n pe fun igbe aye rere fun ọmọ Naijiria.
Wọn ni wọn tun fẹ ki atunto de ba ofin to ni ṣe pẹlu eto idibo, eyi ti wọn ni awọn oloṣelu kan ma n lo lati fi ṣe magomago lasiko idibo.
Kini wọn ni ijọba Buhari ṣe?
Lara awọn ọmọ ẹgbẹ naa to ba awọn akọroyin sọrọ ni ọọfiisi ẹgbẹ ọhun ni ilu Abuja bu ẹnu atẹ lu ijọba apapọ.
Wọn si fẹsun kan an pe ko ṣe ojuṣe rẹ lati daabo bo awọn ọmọ Naijiria lọwọ awọn janduku, awọn adigunjale atawọn aṣẹrubalu to n da ẹmu ara ilu legbodo.
Wọn tun ni asiko ti to fun awọn ọmọ Naijiria rere lati paparapọ lati gba orilẹ-ede yii silẹ lọwọ awọn adari ti ko ni ifẹ ara ilu lọkan.
- Arúfin ni Seyi Makinde pẹ̀lú bó ṣe gbà kí wọ́n sin Ajimobi sí GRA - Amòfin
- Bẹ́ ẹ fẹ́, bẹ́ ẹ kọ̀, July ni ẹjọ́ Sotitobire yóò parí - Adájọ́ gbọmú
- Ẹ dá àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo padà ní kíá - ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
- Wọ́n rí òkú ọmọ ọdún mẹ́fà tí wọ́n fipá bálopọ̀ nínú mọ́ṣálàáṣí ní Kaduna