Fake Lawyer: ₦300,000 ló gbà lọ́wọ́ obìnrin kan, tó sì fẹsẹ̀ fẹ

Ọwọ awọn agbofinro ni ipinlẹ Ogun ti tẹ arakunrin kan to n pe ara rẹ ni agbẹjọro lati fi tu awọn eeyan jẹ.

Ayederu agbẹjọro yii ti orukọ rẹ n jẹ Elijah Ayodeji Ojo, lawọn ọlọpaa sọ pe o ti lo gbajuẹ fawọn eeyan pupọ, to si ti gba owo lọwọ wọn.

Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi lo fidi ọrọ yi mulẹ fun BBC Yoruba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni ọwọ tẹ Elijah lẹyin ti agbẹjọro kan kọ iwe ẹhonu si ọga ọlọpaa Ajuwon wi pe, Ojo ti parọ gba owo lọwọ awọn eeyan pupọ, to si n dibọn pe agbẹjọro ni oun .

Agbẹjọro naa sọ pe afurasi yii ko kẹkọ imọ ofin debi ti yoo kawe gboye lati maa sisẹ agbẹjọro.

Oyeyemi sọ pe, ni kete ti awọn ri iwe ehonu yii ni awọn ọtẹlẹmuyẹ ileesẹ ọlọpaa Ajuwon, labẹ ọga wọn DPO Andrew Akinseye, bẹrẹ iwadii nipa ayederu agbẹjọro naa.

''Nibi ta ti n se iwadii la ti ri arabinrin kan to ni ẹjọ nile ẹjọ, ti afurasi yii si fi ọna eru gba ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira lọwọ rẹ pe, oun fẹ ba pari ilana beeli rẹ, ti ko si pada yọju si ile ẹjọ rara''

Abimbola ni nigba ti awọn ri ẹri to pọ gba nipa rẹ, lawọn mu ti awọn si bẹrẹ si ni fọrọ wa lẹnu wo.

O ni o ti jẹwọ fawọn pe, lootọ ni wọn gba oun wọle si ileẹkọ giga fasiti ipinlẹ Ekiti lati kẹkọọ imọ ofin sugbọn oun ko pari ẹkọ oun nibẹ debi ti yoo lọ si ile iwe imọ ofin (Law School).

Alukoro ọlọpaa wa pari ọrọ rẹ pe, wọn ti gbe lọ si ẹka ọtẹlẹmuye fun ẹkunrẹrẹ iwadii .

Ọwọ àjọ NYSC tẹ ayédèrú àgùnbánirọ̀ 65

Ajọ agunbanirọ, NYSC ti fi awọn ayederu akẹkọjade Fasiti ti wọn gbamu le awọn agbofinro lọwọ.

Awọn eeyan naa ni wọn ri mu ni ibi abala keji ipagọ awọn agunbanirọ to waye kaakiri lorilẹ-ede yii.

Ajọ NYSC ni, awọn eeyan naa lo gbe ayederu iwe ẹri kalẹ ni ibi iforukọsilẹ lati wọle si ibi ipagọ awọn agunbanirọ ọhun.

Ninu atẹjade kan ti ajọ NYSC fi lede, mẹta ninu awọn agunbanirọ ọhun sọ pe wọn kẹkọjade ni Fasiti Istop, to wa ni Cotonou, sugbọn eyi to jẹ irọ funfun balau.

Atẹjade naa ni "Awọn ti a ri mu ninu abala keji iforukọsile ipagọ lọdun ọdun yii jẹ marundinlaadọrin, a si ti fi wọn le awọn agbofinro lọwọ."

Lara awọn agunbanirọ ti ọrọ naa kan ni: Nwachukwu Chimaobi Curtis, Ononuju Amarachi Nwamaka, Francis Joseph Arinze, Chigozie Evidence Chijioke, Iliyasu Usman, Nasiru Yau, Sheu Muktar, Offor Blessing Chinelo, Mezenwa Ngozi Chidinma.

Awọn alakoso NYSC ni awọn ayederu akẹkọjade Fasiti to wa lati oriṣiriṣi Faisiti kakiri orilẹ-ede yii ni ajọ ọhun ti le kuro ni ipagọ awọn agunbanirọ, ti wọn si fi wọn le ajọ ọlọpaa lọwọ ki wọn le foju ba ile ẹjọ.

Oludari eto iroyin fun NYSC, Adenikẹ Adeyẹmi ni, ọga agba fun ajọ ọhun ti kilọ pe, ko si ayederu akẹkọjade Fasiti, nilẹ yii abi loke okun ti yoo kopa ninu eto agunbanirọ mọ.