Coronavirus updates: Ẹ má san ìdámeẹ́wàá tàbí owó ọrẹ lásìkò àrùn Coronavirus - Pásítọ̀ Adewale Giwa

Pasito Ijo Awaiting The Second Coming of Jesus Christ Ministry, Adewale Giwa ti rọ awọn ọmọ ijọ rẹ lati ma ṣe san owo idamẹwa tabi owo ọrẹ titi di igba ti arun Coronavirus ba kuro nilẹ.

Pasito Giwa to sọ eleyii lasiko to n ba awọn ọmọ ijọ rẹ sọrọ ni kii ṣe ohun to dara ki iya ma a jẹ awọn eniyan, ki wọn si ma a san owo idamẹwa.

O ni ohun ti ko dara ni ki eniyan san ọrẹ atinuwa, amọ ki o ma ṣe afagbara ṣe nitori nkan lera fun awọn eniyan lasiko yii.

Amọ, pasitọ naa bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ijọba to pọn dandan fun awọn ọmọ ijọ lati wọ ibomu ti wọn ba n lọ si ile ijọsin, to si rọ ijọba lati dawọ igbesẹ naa duro.

Bakan naa lo fikun wi pe ko ṣeeṣe ki ile ijọsin ṣe ẹsin fun wakati kan pere, o ni ijọba gbọdọ ṣe ayẹwo ati atunto aṣẹ to rọ mọ ki ile ijọsin si pada kaakiri orilẹede Naijiria.