You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Dagrin: Ikú Dagrin pé ọdún méjìlá, wo àwọn ǹkan mánigbàgbé nípa rẹ̀
Oni yii gan-an lo pe ọdun mejila ti Oladapo Olaitan Olaonipekun, ti gbogbo awọn eniyan mọ si Dagrin, di oloogbe.
Yatọ si Dagrin, awọn orukọ bii Barack O'Grin, Lyricle Wayray, Akogun, Omo ogun, ni wọn tun mọ ọ si.
Ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Kẹwa ọdun 1984 ni wọn bi, ṣugbọn o ku lẹni ọdun mẹẹdọgbọn, ni ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2010 lẹyin to ni ijamba ọkọ nilu Eko.
Ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹrin ni ijamba alagbara naa waye, lasiko ti ọkọ ayọkẹlẹ rẹ forigbari pẹlu ọkọ akẹru kan ni adugbo Mushin.
Ileewe alakọbẹrẹ Meiran Community Primary school, Roseille nursery and primary school, Meiran Community High school, ati Egbado College lo lọ.
Iya rẹ ni iyawo kẹta ninu iyawo mẹta ti baba rẹ ni
Baba rẹ jẹ oniṣowo rẹkọọdu orin, o si ni ile itaja kan, House of Nelly sounds, ni ibudokọ Meiran nigba kan.
Nigba aye rẹ, orukọ Dagrin lori Twitter ni @Dagrinfimile, o si n lo Dagrin fimilejo lori Facebook. Ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2010 lo lo ayelujara Twitter gbẹyin.
Lootọ lo ti ku, awọn eniyan ṣi n fi ọrọ iranti si oju opo Twitter rẹ.
Ọna ti Dagrin n gba kọ orin rẹ gbajumọ pupọ laarin igboro nigba naa, nitori pe awọn orin rẹ ma n ba idojukọ ogunlọgọ awọn ọdọ Naijiria mu.
Awo orin rẹ, Chief Executive Omota, gba ami ẹyẹ Hip hop World Award fun orin 'rap' lọdun 2010.
O ba awọn akọrin bi i 9ice, Y.Q, M.I, Iceberg Slim, Omobaba, Terry G, Omawumi, ati Konga kọrin pọ.
Orin 'if I die', to tu mọ si 'Ti mo ba ku', lo gbe jade kẹhin. Ko si pẹ ti orin naa jade lo ku. Eyi to mu ki ọpọ o sọ nigba naa pe boya o ti mọ pe oun fẹ ẹ ku lo ṣe kọ orin naa.
Diẹ lara awọn orin to kọ ni:
- Pon pon pon
- Kondo
- If I die
- Rap Rules ANTHEM
- Everyday
- Ni 94
- Where Ya 94
- SISI eko
- Ghetto Dreams
- Loni Ni
- Democracy
- Thank God