Olisa Metu: Ilé ẹjọ́ rán Olisa Metuh sẹ́wọ̀n ọdún méje

Olisa Metuh

Oríṣun àwòrán, @FocusOgun

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

ile ẹjọ giga ilu Abuja ti ran agbẹnusọ tẹlẹ fun ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, Olisa Metuh lọ si ẹwọn ọdun meje.

Adajọ Okon Abang da ẹjọ naa lọjọ iṣẹgun ọsẹ lori ẹsun siṣe owo maku-maku ati yiyi owo da si tir ti gbogbo rẹ to irinwo miliọnu naira.

Bakan naa, adajọ paṣ pe ki ileeṣ Olisa Metuh, Dextra investment san faani miliọnu mẹẹdọgbn naira ni ibamu pẹlu ẹsun ikarun ati ikẹfa ti wọn si paṣẹ pe ki Olisa Metuh funra rẹ san faani ọọdunrun le marunlelaadọrin miliọnu naira.

Ile ẹjọ giga niluu Abuja ri aridaju pe Ọgbẹni Olisa Metuh jẹbi gbogbo ẹsun ti wọn fi kan an lori owo irinwo miliọnu naira pe o gba lọwọ Sambo Dasuki laye ijoba Jonathan.

Ninu ẹjọ naa ti adajọ Okon Abang ti ile ẹjọ giga ni ilu Abuja da, wọn ni Ọgbẹni Olisa Metuh jẹbi ẹsun ti ajọ EFCC fi kan an.

Ajọ EFCC fi ẹsun meje tan yanyan kan Metuh ti o jẹjọ papọ pẹlu ile iṣẹ rẹ, Destra Investment.

Ṣe ni Olisa Metuh rin wọ inu ile ẹjọ bi ẹni ti ko ni iṣoro kankan, ẹwẹ ko tii mọ iru idajọ ti yoo gba lonii.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Awọn igba ti Olisa Metuh ti foju ba ile ẹjọ ri

Olisa Metuh

Oríṣun àwòrán, @FocusOgun

Wọn fi ẹsun kan agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu PDP tẹlẹri yii lórí iye owo to to irinwo miliọnu naira (N400,000,000).

Atoun ati ile iṣẹ rẹ, Destra Investment ni ẹjọ yii kan eyi to nii ṣe pẹlu ẹsun meje ọtọtọ lori yiyi owo ti o gba lọwọ olugbaninimọran lori ọrọ abo tẹlẹ ri, Ogagun Sambo Dasuki si tirẹ.

Ninu aworan isalẹ yii, iyalnu lo jẹ lọjọ yii to yẹ ki Olisa Metuh fara han nile ẹjọ ti gbogbo eeyan si dede ri i lori ibusun alaarẹ ati ike iwosan lọrun rẹ.

Olisa Metuh wọ ile ẹjọ lori ibusun alaarẹ

Oríṣun àwòrán, Leadership Newspaper

Bakan naa, wọn fi ẹsun kan Metuh lori iye owo miliọnu meji dollar kan ti ko gba banki kankan kọja rara eyi si ni ajọ EFCC ni o lodi si ofin.

Ninu oṣu karun ọdun 2018, lasiko ti igbẹjọ n lọ lọwọ, ṣaa dede ni agbẹnusọ fun ẹgbẹ oṣelu PDP tẹlẹ ri, Olisa Metuh ṣubu yakata silẹ nigba ti wọn pe e to fẹ maa rin lọ sinu koto ijẹjọ to si fa ariwo hee nile ẹjọ.

Olisa Metuh ṣubu yakata nile ẹjọ

Oríṣun àwòrán, Premium Times - Evelyn Okakwu

A gbọ pè aisan to n ba a finra ni ṣe pẹlu ifarapa egungun ẹyin to si ti mu u farahan nile ẹjọ lọpọ igba lori ibusun alaisan.

Olisa Metuh nile ẹjọ

Oríṣun àwòrán, @SheunDam

Gbogbo igbiyanju lati jẹ ki wọn sun igbẹjọ rẹ siwaju ko baa le lọ fun itọju loke okun ni ile ẹjọ ko gba rara.

Ninu oṣu kinni ọdun 2016, Metuh ni oun ko jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an.

Olisa Metuh pẹ̀lú awọn oṣiṣẹ EFCC

Oríṣun àwòrán, @pitharoy