Metuh ni lati yọju sile ẹjọ ni osu to n bọ

Oríṣun àwòrán, Metuh/Twitter
Ilé ẹjọ̀ giga ilu Abuja ti pasẹ fun agbẹnusọ fun ẹgbẹ̀ PDP tẹ̀lẹ́rí, Ọ̀gbẹ́ni Olisa Metuh kí ó yọjú sí ilé ẹjọ̀ fun ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ karun, osù kejì ọdún yíí.
Adájọ́ àgbà Okon Abang ló pasẹ naa nígbàtí ó ń gbẹ́jọ́ tí Metuh pè, tó n bèèrè ki ile ẹjọ́ sún ejọ́ òun síwájú nítorí àilera oun.
Adajọ naa so wipe lẹta ti Metuh fẹki ile ẹjọ fi se eri lati sun ẹjọ siwaju kii se eri to munadoko.
"Mo faramọ oun ti agbẹjọro EFCC sọ, pe lẹta ti wọn ni Dr O.C Ekweogwu kọ, eni ti ile ẹjọ yi ko mọ, je iwe lasan, to ye fun akitan ni wọn gbe le ile ẹjọ yi lọwọ."
"Ona eru ni wọn fi gbe lẹta na wọ inu iwe akọsilẹ ile ẹjọ yi, lero ati fi da ẹjọ duro."
Adajo tun te siwaju nigbati o so wipe, ona ti o tọ wa lati fi iwe to ba jọ mọ ilera eniti o ba n jẹjọ. O ni kii se etọ dokita lati kọ iwe jaaran jaaran ati awọn ọrọ̀ ti ko ni itumo si ile ẹjọ.
"Dokita ni lati sọ orukọ aisan ati iwọn igba ti eni naa yoo fi wa ni idubulẹ̀."
Wọn fi ẹ̀sun kan Metuh wipe o gba owo to to inrinwo milionu naira lọwọ olubadamọran lori ọrọ abo tẹlẹri, ajagun feyinti Sambo Dasuki, ati lori iwa ijẹkujẹ to fi mọ sise owo ti o to bilionu meji naira balubalu.












