Kara Market Fire: Iná sọ ní ọjà Kara l'ọ́dún ku ọ̀la

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ina nla kan ti burẹkẹ ni Ọja nla Kara to wa lopopona Eko si Ibadan.

Ọja yii ni wọn ti n ta ẹgbọrọ maalu, agbo, ewurẹ tabi aguntan.

Ni akoko ti a n ko iroyin yii jọ, a ko ti ri aridaju ohun to fa ina yii ṣugbọn iṣẹlẹ naa ti mu ki sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ gberasọ ni opopona ọhun.

A n se akojọpọ ẹkunrẹrẹ iroyin yajoyajo lọwọ, a o maa gbe ẹkunrẹrẹ iroyin naa sori atẹ iroyin wa laipẹ. Ẹ jọwọ, ẹ tun oju opo iroyin yi yẹwo, ki ẹ lee ri ẹkunrẹrẹ iroyin ọtun laipẹ.