Mobile App: Àsìkò tó wu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ni olùkọ́ máa jáde wa kọ́ wọn láti inú fóònù wọn

Àkọlé fídíò, Mobile App: Àsìkò tó wu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ni olùkọ́ máa jáde wa kọ́ wọn láti inú fóònù wọn

Mobile Classroom App wa fun iranti gbogbo akẹkọọ- Akemem Salami

Ogbeni Akeem Salami to ṣe agbekalẹ Mobile Classroom App ni BBC Yoruba ba sọrọ lori idi pataki to ṣe ṣagbekalẹ ẹrọ igbalode naa.

O ni ko yẹ ki akẹkọọ kuna mọ ninu idanwo aṣekagba iwe mẹwaa ati ti aṣewọle ile iwe giga mọ ni orilẹ-ede Naijiria.

Koda, Salami ni iṣẹ olukọ ti gba irọrun nitori ori foonu akẹkọọ ni olukọ ati jade ba akẹkọọ sọrọ

Ogbeni Akeem ni gbogbo iṣẹ inu ẹka ẹkọ lo wa ninu ẹrọ igbalode naa titi de ori Yoruba.

Eyin ti ẹ ba fẹ kọ ede Yoruba sii tun le mọ siwaju nipa ede abinibi yin lati ori App naa.