Nobel Peace Prize 2019: Adarí ìjọba ilẹ̀ Ethiopia, Abiy Ahmed gba àmì ẹ̀yẹ

Oríṣun àwòrán, Reuters
Wọn ti kede Abiy Ahmed ti o jẹ Olotu Ijọba ilẹ Ethiopia gẹgẹ bi ẹni ti o gba ami ẹyẹ Alafia ti agbaye ọdun 2019.
O gba ami ẹyẹ yii latari ipa ti o ko ninu mimu alaafia jọba ati ifọwọsowọpọ awọn orilẹ ede agbaye.
Ilẹ Ethiopia ni o fọwọ sowọpọ pẹlu Eritrea ni ọdun to kọja ti ajọṣepọ naa yoo si lo bii ogun ọdun ti o si nii ṣe pẹlu ọrọ ibode ni ọdun 1998 si 2000.
Wọn fun un ni ami ẹyẹ yii ni ipele ọgọrun iru rẹ ti o waye ni Oslo.
Yoo gba ami ẹyẹ yii ti o si to bii milliọnu mẹsan owo ilẹ Sweden ti yoo waye ni oṣu kejila.
Ko din ni Ọọdunrun oludije ti wọn fifẹ han lati jẹ olubori to fi mọ awọn eeyan bi Okoolelugba ati ọpọ ẹlẹgbẹjẹgbẹ to jẹ metalelọgọrin fun ami ẹyẹ.
Ti wọn si ti n woye pe ta ni yoo jawe olubori, ti ọpọ si ti fi ọkan si Greta Thunberg, olumọ nipa oju ọjọ.
TA NI ABIY AHMED?
Lẹyin ti o di Olotu Ijọba ilẹ Ethiopia ni oṣu kẹrin ọdun 2018, o ṣe agbekalẹ eto lati mu ayipada rere ba ilẹ naa ti o si mu iyatọ ba orilẹede ọhun.
Bakan naa lo tun fi ọgọọrọ awọn ọmọ ẹgbẹ alatako silẹ ni ọgba ẹwọn ti o pe gbogbo awọn ti o ti fi ilu silẹ pada wale.
Eyi ti o ṣe ti o ṣe pataki julọ ni pe o fọwọ si iwe alaafia pẹlu orilẹede ti o wa ni ẹgbẹ wọn, Eritrea ti o si to bii ogun ọdun ti iwe ibaṣepọ naa yoo fi fẹsẹ mulẹ.
Ninu atunto ati atunṣẹ ti o ṣe ni ija ẹlẹyamẹya ti o fopin si ti o si ti le bii milliọnu meji awọn eniyan kuro ni ile wọn.
Aarẹ Buhari naa ki Olotu IjọbaEthiopia fun jijawe olubori ninu ami ẹyẹ naa ati fifi opin si ija laarin Ethiopia ati Eritrea lati bii ogun ọdun sẹyin.
Buhari lo fi ọrọ yii lede lori ẹrọ ayelujara rẹ ni ọjọ eti lati ba Olotu naa yọ fun aṣeyọri ati gbigba ami ẹyẹ naa.












