Zainab Habib: Bí ẹ se gba Zainab sílẹ̀, ẹ gba Leah Sharibu lọ́wọ́ Boko Haram’

Oríṣun àwòrán, Google
Ajọ ọmọ lẹyin Kristi, CAN ti apa ariwa orilẹede Naijiria ti ba awọn obi Zainab Aliyu yọ lori pe wọn gba itusilẹ rẹ.
Ajọ CAN to bu ẹnu atẹ lu atimọle awọn ọmọ Naijiria lọna aitọ, tun ke gbajari si ijọba apapọ lati wa ọna lati gba itusilẹ Leah Sharibu to ti wa ni panpẹ ikọ Boko Haram lati Osu Keji, ọdun to kọja.
Ọpọlọpọ ariyanjiyan n lọ lori ipa ti ijọba ko lati gba itusilẹ Zainab lọwọ ijọba Saudi nigbati Sharibu ṣi wa ni panpẹ Boko Haram.
Ajọ CAN naa wa ke si aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari lati dari awọn eleto aabo ati ile-isẹ ologun Naijiria lati rii wi pe wọn se ohun to yẹ lati gba Leah Sharibu to jẹ ọmọ lẹyin Kristi naa silẹ.









