#BBCGovDebate: Àwọn olùdíje nípinlẹ̀ Eko yóò figagbága
Nibayii ti eto idibo gbogbo gboo n kanlẹkun gbọn-gbọn ni orilẹ-ede Naijiria, oniruuru aayan ni ileesẹ BBC Yoruba ti n ṣe lati rii daju pe awọn araalu ni anfaani lati yan aarẹ, awọn gomina ati awọn aṣofin to pegede, lati le fi gbọọrọ jẹka.
Yatọ si pe a n kede awọn iroyin nipa eto idibo to n bọ naa loore-koore, BBC Yoruba ti ṣeto lati ṣe ariyanjiyan fawọn eeyan to n dije lati du ipo gomina ninu eto idibo naa, paapa awọn to wa lẹkun ilẹ Oodua.
Ipade itagbangba ti ipinlẹ Kwara ti waye bẹẹ si ni , gẹ́gẹ́ bí BBC Yoruba ti ṣide ipade itagbangba naa, ni ti ipinlẹ Eko, eto ariyanjiyan yoo waye laarin awọn oludije latinu ẹgbẹ oselu mẹrin n tawọn eeyan nifẹ si.