Epo rọ̀bì: Ẹgbẹ́ oníṣòwò epo fẹ́ daṣẹ́ sílẹ̀ lóró owó t'ìjọba jẹ wọ́n

O n rugbo bọ, awọn la dẹẹ dee, ẹgbẹ oniṣowo epo rọbi ti fun ijọba apapọ ni gbedeke ọjọ meje lati san gbese ẹgbẹrin biliọnu naira owo ajẹmọnu ori epo, bi bẹẹ kọọ, awọn yoo da isẹ silẹ nibi gbogbo ibudo igbepo.

Oludamọran lori ọrọ ofin fun ẹgbẹ oniṣowo epo rọbi Ọgbẹni Patrick Etim ṣalaye pe awọn ile ifowopamọ ti gbẹsẹ le idoko-owo awọn oniṣowo epo latari gbese ti wọn ko tii san.

Ọgbẹni Etim sọ pe ko si ohun ti ẹgbẹ onisowo le ṣe ju ki wọn sọ fun awọn osiṣẹ wọn lati duro sile nitori owo oṣu ti wọn n jẹ wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O fikun ọrọ rẹ pe ọna abayọ ni pe ki ijọba san owo ti o jẹ awọn oniṣowo epo ni kiakia.

Ọgbẹni ni ijọba apapọ ti kuna lati mu ileri rẹ ṣẹ lori owo ti o n jẹ awọn oniṣowo epo rọbi.

O tun sọ pe ọrọ naa yoo sọ ọpọ eeyan di alainiṣẹ lọwọ mọ nitori awọn oniṣowo epo ti fẹ din awọn oṣiṣẹ wọn ku nitori ko si agbara lati maa sanwo oṣu gbogbo wọn mọ.