You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Fisa Atiku: Ọ̀pọ̀ aráàlú dunú, àwọn míràn yẹ̀gẹ̀ rẹ̀
Ọjọ Abamẹta ni iroyin kan gbalẹ pe, Oludije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu PDP, Atiku Abubakar, ti ni anfaani bayii lati se abẹwo si orilẹede Amẹrika pẹ̀lu bi ọwọ rẹ se ba iwe asẹ irinna silẹ Amẹrika.
Iroyin naa ni ọdun kẹtala ree ti Atiku ti ni anfaani kẹyin lati se abẹwo si orilẹede Amẹrika nitori ẹsun ajẹbanu ti wọn fi kan lori ọrọ epo rọbi lasiko to jẹ igbakeji aarẹ fun Oloye Olusẹgun Ọbasanjọ.
A gbọ pe ilu Abuja ni Atiku ti lọ gba iew asẹ irinna si Amẹrika naa, ti inu rẹ si dun dẹyin pe ọwọ oun tẹ ‘Fisa’ naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ni kete ti iroyin ọhun gbalẹ kan lawọn Naijiria ti n fi ero wọn nipa iroyin naa han lawọn oju opo ikansiraẹni lori ayelujara, paapa loju opo Twitter.
@G_Abdulazeez, o yọ suti ete si iroyin yii, to si ni nibayii ti Atiku ti gba, aseyọri nla ni eyi fawọneeyan to pe ‘onijẹkujẹ’ati ẹgbẹ oselu PDP pẹlu afikun pe ara oun n wa galegale lati dibo.
@OtunbaSula, o ni inu oun dun lati gbọ pe Atiku ti ri fisa Amẹrika gba, to si n ki awọn ololufẹ Atiku yoku ku oriire.
@WazirinBuhari n tiẹ ni to ba jẹ lootọ ni Atiku gba fisa, eyi pa ni lẹrin, amọ se o lee lọ si Amẹrika bi?
@Noelema2, o n beere pe "ki ni igbesẹ gbigba fisa Amẹrika nii se pẹlu akoso ijọba Naijiria? Koda bi Atiku gan jẹ ọdaran to buru julọ lagbaye, o si san ju Buhari lọ. "A ko nilo fisa Amẹrika kankan, akoso to yanranti la nilo. N jẹ Trump gan ti wa si Naijiria ri, se Obama de Naijiria ri?"