Ẹgbẹẹgbẹrún ní oró ejò ń pa lọdọọdún

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àjọ tó ń mójútó ètò ìlera lágbàyé (WHO) ni iṣẹ́ ń bẹ niwaju ìjọba orílẹ̀-èdè gbogbo lórí ìtọ́jú oró ejò sùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn elétò ìlera kò kàákún
Wọn ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn ló ń kú lọ́dọọdún tí ọ̀pọ̀ sì di aláàbọ̀ ara nípàsẹ̀ oró tí ejò pọ̀ sí wọn lára lásìkò tó bù wọn jẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àjọ elétò ìlèra àgbáyé sọ pé pẹ̀lú gbogbo ìnira tó ń bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà rìn síbẹ, o jẹ́ ọkan lára etò ìlera tí ẹnikẹ́ni kò kọbiara sí.
Fún ìdí èyí ni àwọn orílẹ̀-èdè lábẹ́ àjọ WHO ṣe fẹnukò láti sètò ọ̀nà láti dẹ́kun, tójú àtí láti ṣe gba ìsàkóso ìtójú oró ejò.
BBC Yorùbá ṣe ìwádìí láti mọ ipò tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wà lórí ìtójú àwọn tí ejò bùjẹ àti pé irú ètò wo ló wà nílẹ̀ fún wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ìwádìí BBC Yorùbá
Dókítà Francis Duru ti ile-ìwòsàn LASU ní ìpínlẹ̀ Ekó ṣàlàyé ipò tí ìtójú ẹni tí ejò bùsan ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wa
Ọ̀nà wo ní a lè gbà dá ejò olóró mọ̀:
- kọ́kọ́ yẹ orí rẹ̀ wò: ọ̀pọ̀ ejò olóró máa ń ní orí onígun mẹ́ta
- Ó máa ń ní àwọ̀ tó mọ́
- Àwọn míràn máa ń wo inú ojú rẹ̀ (sugọn ní ọ̀pọ̀ igbà eyí kìí ṣe ẹ̀rí tó dájú)
- Wo ihò tó wà láàárín ojú àti imú ejò náà
- Ejò tó máa ń darapọ̀ mọ́ àyíká
- Ṣe àyẹ̀wò ojú ibi tí ejò ti bùyàn jẹ tí ó bá ní ojú méjì











