You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ààrẹ Buhari padà sílé lẹ́yìn ìpàdé pẹ̀lú ààrẹ Trump
Lẹ́yìn ìbẹ̀wo isẹ́ sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà níbi tó ti fọ̀rọ̀jomitoro ọ̀rọ̀ fún ìbásepọ̀ pẹ̀lú ààrẹ Donald Trump, ààrẹ Muhammadu Buhari ti padà dé sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lálẹ́ ọjọ́rú.
Ìròyìn tó ni létí pé, ọkọ̀ bààlù tí ó gbé ààrẹ àtàwọn tó kọ́wọ̀ọ́ rìn pẹ̀lú ẹ̀ gúnlẹ̀ sí apá kan tó wà fún ààrẹ́ ní pápákọ̀ òfurufú Nnamdi Azikwe nílu Abuja ní ǹkan bí ago mọ̀kànlá ku ìsẹ́jú márunlélógún alẹ́.
Lára àwọn tó kí ààrẹ Buhari kú àbọ̀ ní pápákọ̀ òfurufú ni Mínísítà fún olú ìlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Malam Musa Bello, olórí àwọn ọmọ ogun sí ààrẹ, Malam Abba Kyari àtàwọn olóri àwọn òsìsẹ́ aláàbò.