Ìjọba Nàìjíríà; Ohun burúkú ni láti pa àwọn olùjọ́sìn

Àwọn osise isele pajawiri
Àkọlé àwòrán, Ènìyàn tó lé lọ́gọ́ta lo fara káasa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Ijọba orilẹede Naijiria ti bu ẹnu atẹ lu isekupani pẹlu ado oloro to waye ni mọsalasi ati ọja to wa ni Adamawa ni ila-oorun ariwa orilẹede Naijiria.

Ibugbamu ado oloro naa ni wọn sọ wi pe, awọn ọdọkunrin meji naa se ni agbeegbe Mubi, eyi ti ko jinna si Yola, to jẹ Olu-iIu ipinlẹ Adamawa.

Ijọba apapọ lori itakun ikansiraẹni, Twitter ni, awọn ti pasẹ fun awọn ẹsọ alaabo lati gbe igbesẹ to peye ki aabo to kun ojuwọn lee wa ni agbegbe Mubi.

Ninu ọrọ tirẹ, igbakeji aarẹ, Yemi Ọsinbajo to ba gomina ipinlẹ Adamawa kẹdun, ni ki ajọ to n sakoso isẹlẹ pajawiri ( NEMA) tete pese ohun ti awọn to farapa ninu ikọlu naa nilo lasiko.

Amin iyasọtọ kan

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Fídíò òògùn ikọ́ Codeine: Ó dùn lóòtọ́ àmọ́ ewu ni
Amin iyasọtọ kan

Bo tilẹ je pe ẹgbẹ agbesunmọmi kankan ko ti farahan wi pe awọn la wọn se ikọlu naa, awọn eniyan gbagbọ wi pe ikọ Boko Haram lo seese ki wọn se ikọlu naa ni Adamawa.