BBC: A fẹ mọ idi tijọba Eko fi kọlu akọroyin wa

Ami idamọ BBC
Àkọlé àwòrán, BBC nfẹ kijọba ipinlẹ Eko fun awọn akọroyin lominira alti sisẹ wọn laisi atako

Ileesẹ agbohunsafẹfẹ BBC ti bu ẹnu atẹ lu iwa abuku ti awọn osisẹ ijọba ipinlẹ Eko se si akọroyin wọn kan nigbati wọn fi tipa-tipa gba ẹrọ agbohunsilẹ akọroyin naa, ti wọn si pa aworan to ka silẹ nibẹ rẹ.

Abule mekaniki to wa lẹba ibudo idalẹsi Olusosun ladugbo Ọjọta nibiti eefin nla pẹlu afẹfẹ oloorun buruku ti gba ile kan ni isele naa ti waye.

Joshua Ajayi, tileesẹ BBC Yoruba se sabẹwo si abule atọkọse naa lati bawọn mẹkaniki naa sọrọ, sugbọn asiko yii ni awọn osisẹ ileesẹ ọrọ ayika ya bo ibẹ lati gbe ilẹkun ibẹ ti, ti wọn si fi tipa gba ẹrọ agbohunsilẹ akọroyin naa.

Nise ni ikọ ẹlẹni mẹfa naa, ti igbakeji oludari nileesẹ ọrọ ayika, Awoniyi Joshua ko sodi, so wi pe awon yoo fi akọroyin BBC si ahamọ.

Gbogbo alaye ti akoroyin wa se pe ki won jọwọ ẹrọ ibanisọrọ to fi ya aworan ibudo naa fun ohun ko wo eti awọn iko naa.

Lẹyin ọrẹyin ni akọwe agba nileesẹ ọrọ ayika, Abiọdun Bamgboye, wa da ẹrọ ibanisọrọ naa pada sugbọn gbogbo aworan ati ohun mẹtadinlogun to wa ninu rẹ, ni wọn ti parẹ patapata.

Ileesẹ BBC ni " ohun to nkọni lominu gbaa ni isẹlẹ yii, ti a si nbeere alaye ni kiakia lọwọ awọn alasẹ idi ti wọn fi se bẹẹ. Ileesẹ BBC wa nkesi ijọba lati fun awọn akọroyin lanfaani lati sisẹ wọn pẹlu ominira to peye ati ododo lati atako lati ibikibi."

Gomina Akinwunmi Ambode

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ijọba gomina Akinwunmi Ambode tọrọ aforijin lori ikọlu tawọn osisẹ rẹ se si akọroyin BBC

Ijọba Eko tọrọ Aforijin lọdọ BBC

Ni aarọ ọjọ aje, kọmisọna fọrọ ayika nipinlẹ Eko, Babatunde Durosinmi-Ẹtti fi atẹjade kan sita fun ileesẹ BBC, o ni " Ni orukọ ileesẹ naa, mo tọrọ aforijin, kii se lorukọ ileesẹ naa nikan, ati lorukọ ijọba ipinlẹ Eko pẹlu, a si pada se agbeyẹwo isẹlẹ yii."

"Nitori kii se asa wa, tabi ise awọn asaaju ijọba yii, bẹẹ ni awọn asaaju ijọba Eko ko ni faramọ irufẹ iwa yii."

Awọn ara adugbo olusosun ke gbajare si ijoba

Ewe, Igbakeji alaga fun ibudo atọkọse naa, Ọlaniyi Adeoti, ti sọ saaju fun akọroyin BBC pe awọn asoju wọn ti kọkọ lọ ri awọn osisẹ ileesẹ ọrọ ayika ni Alausa nigba to ku wakati diẹ ki wọn wa le awọn kuro ni ibudo naa.

O ni o ba oun lojiji pe lẹyin wakati kan soso pere ti ipade naa pari, lawọn osisẹ ileesẹ naa wa lati ti abule mẹkaniki yii lai jẹpe wọn fun awọn ni anfaani tabi akoko diẹ si lati ko lọ si ibudo mii.

Ẹ gbo oun ti wọn so ninu fidio yi:

Àkọlé fídíò, 'Ijọba fẹ le wa kuro ni Ọjọta'

Iroyin miran t ni fẹsi