Ondo:Igbìmọ̀ eré ìdárayá di títúká

Saka Yusuf Ogunlẹyẹ-Kọmísónnà fún eré ìdárayá àti ìdàgbásókè àwọn ọ̀dọ́ nípínlẹ́ Ondo

Oríṣun àwòrán, facebook/Saka Yusuf Ogunleye

Àkọlé àwòrán, Saka Yusuff Ogunlẹyẹ ni ijọba ipinlẹ Ondo nla kaka lati mu igbega ba ere idaraya ni.

Kọmísọ́nà fún eré ìdárayá àti ìdàgbásókè àwọn ọ̀dọ́ nípínlẹ́ Ondo, Saka Yusuf Ogunleye ti kéde pe wọn ti tu gbogbo ìgbìmọ̀ eléré ìdárayá ka nípínlẹ́ Ondo.

Ogunleye sọ wípé ojú ẹsẹ̀ náà ni àsẹ tò tù awọn ìgbìmọ̀ náà ká bẹ̀rẹ̀ sí ní mulẹ, tó sì kìlọ̀ pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ kede ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi alága ìgbìmọ̀ eré ìdárayá kankan.

Asia ile-ise to n risi ere boolu ni ipinle Ondo

Oríṣun àwòrán, ODSFA

Àkọlé àwòrán, Ijọba ipinlẹ Ondo ni laipẹ loun yoo se agbekalẹ awọn igbimọ elere idaraya tuntun

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, O wípé láìpé yìí làwọn yóò dà oniruuru ẹlẹgbẹjẹgbẹ ere idaraya tuntun sílẹ̀, tí yóò ri dájú wípé eré ìdárayá nidàgbàsókè nípínlẹ́ náà.

Kọmísónnà fún eré ìdárayá náà fikún pé ìgbésẹ̀ tuntun yìí wáyé lati fi agbárá kún akitiyan ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo lati ri daju wípé ìtẹ̀síwájú dé bá ọ̀rọ̀ eré ìdárayá ìpínlẹ́ náà.