You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Bàálù to gbe Yemi Oṣinbajo já lulẹ̀ ní Kogi
Iroyin to n tẹwa lọwọ ni pe ọkọ baalu Igbakeji Aarẹ Naijiria, Yẹmi Ọṣinbajo ja lulẹ ni ilu Kabba nipinlẹ Kogi laipẹ yii.
Amugbalẹgbẹ rẹ, Laolu Akande lo fi ikede naa sita loju opo Twitter rẹ.
A gbọ wipe lasiko ti baalu ayarabiaṣa naa fẹ ẹ ba lo ja lojiji. Ṣugbọn Ọṣinbajo ati awọn ti wọn jọ wa ninu baalu naa ko ni ifarapa kankan.
Ko pẹ ti ijamba naa waye ni Ọṣinbajo fi fidio kekere kan soju opo Instagram rẹ. O sọ ninu ọrọ rẹ pe ''Gbogbo ogo fun Ọlọrun, baalu ayarabiaṣa to gbe wa lati ilu Abuja ja lulẹ nigba to fẹ ẹ ba silẹ nilu Kabba, nipinlẹ Kogi.
Emi ati awọn ti a jọ wa ninu rẹ wa ni alaafia, a si n tẹsiwaju ninu eto 'Next level' wa ati ipinnu wa fun ipinlẹ Kogi."