Trump-Mo ni ọwọ nla fun ilẹ Afrika

Aarẹ ilẹ Amẹrika, Donald Trump ti fi iwe sọwọ sibi ipade awọn orilẹede nilẹ adulawọ to nlọ lọwọ nilu Addis-Ababa, lorilẹede Ethiopia.
Ninu lẹta naa lo ti kede pe oun ni ọwọ to jinlẹ fun ilẹ Afrika toun yoo si fi awọn asoju ilẹ Amẹrika to dantọ ransẹ lọ sibẹ.
Iwe yi si lo fi sọwọ lẹyin ọrọ kan ti Trump fi ransẹ ibinu sawọn assaju ilẹ Afrika losu taa wa yi nibi to ti pe awọn orilẹede adulawọ ni salanga ati akitan.
Biotilẹjẹpe Trump ti sẹ kanlẹ lori ọrọ naa, amọ ireti wa pe o seese kawọn asaaju ilẹ Afrika bii marundinlaadọta to wa ninu ajọ isọkan ilẹ Afrika (AU), bu ẹnu atẹ lu ọrọ yi.
O seese kawọn asaaju ilẹ Afrika bu ẹnu atẹ lu ọrọ abuku Trump.
Ninu iwe to kọ ohun, ni aarẹ ilẹ Amẹrika ti ni "mo fẹ tẹnumọ pe ilẹ Amẹrika ni ọwọ ati iyi to pọ fun ilẹ Afrika, ti mo si tun mu ibasepọ to lagbara ati eyi to ni ọwọ pẹlu awọn orilẹede nilẹ Afrika gẹgẹbi orilẹede olominira lọkunkundun."
"Awọn ọmọogun wa n ja fitafita lati sẹ eegun ẹyin awọn adunkoko mọni, bẹẹ si la tun n sisẹ kara lati se agbekalẹ ibasepọ okoowo to jẹ ọfẹ ati eyi ti ko ni magomago ninu."








