Super Eagles fi ọdun meji kun isẹ Gernot Rohr

Olukọni fẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles, Gernot Rohr

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Olukọni fẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles, Gernot Rohr

Olukọni fun ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles, Gernot Rohr ni wọn ti fi ọdun meji miran kun adehun isẹ rẹ, lẹyin ti wọn se adehun tuntun pẹlu rẹ.

Rohr, to jẹ ọmọ orilẹede Germany, lo yẹ ki adehun isẹ rẹ pẹlu egbe agbabọọlu Super Eagles pari losu mẹfa sasiko yi.

Idi ti wọn fi se adehun isẹ tuntun pelu re ni wipe, o se aseyọri lati mu ki ikọ agbabọọlu Super Eagles yege lati kọpa ninu idije ife ẹyẹ Agbaye (World cup) ti yoo waye lorilẹede Russia lodun yi (Russia 2018).

Adehun isẹ tuntun pelu Gernot Rohr si ni yoo wa fun odun meji miran.

Tẹẹ ba gbagbe, Rohr ti dari ikọ agbabọọlu orilẹede Burkinaso ati Niger Republic, ko to darapo mo ẹgbẹ agbaboolu Super Eagles tilẹ wa lodun 2016.