Tunde Bakare: Ìgbà ọ̀tun ni yóò jẹ́ fún àwọn ọmọ Naijiria tí mo bá gba ìjọba

Adari ijọ Citadel Global Community, Pasitọ Tunde Bakare ti kesi awọn ọmọ Naijiria lokeere pe ti wọn ba dibo fun oun, iwuri ni Niajiria yoo jẹ fun wọn lasiko diẹ si.

Pasitọ Bakarẹ sọ eyi lasiko to n ṣe ipade lori ẹrọ ayalujara lori akori to safihan ohun mẹrindinlogun to fẹ ṣe fun awọn ọmọ Naijiria, " 'Unveiling Project 16 to Nigerians in Diaspora'.

Bakare, to n ba awọn ọmọ Naijiria lokeere sọrọ ni, idi ti oun fi n dije dupo aarẹ ni ọdun 2023 ni lati mu igba ọdun de ba orilẹede Naijiria, 'The portrait of a new Nigeria'.

Igba akọkọ kọ ni yii ti pasitọ Bakare yoo ma a dije dupo aarẹ lorilẹede Naijiria, oun pẹlu aarẹ Muhammadu Buhari ni wọn jọ dije dupo ni ọdun 2011 labẹ ẹgbẹ oṣelu ''Congress for Progressive Change ''.

Lasiko to n sọrọ lori ipinnu rẹ ti o ba di aarẹ, ni pasitọ naa ti sọ wi pe orilẹede Naijiria yoo ri igba ọtun, ti ko si ni ṣe ajoji si ẹnikẹni.

''Oun ti mo fẹ ni igba ọtun fun awọn ọmọ Naijiria lai ni ainiaini ninu. Nkan ti mo duro fun ni yii''.

O tunmọ si pe gbogbo iha ati ẹkun ni Naijiria, to fi mọ Guusu, Ariwa, Ila Oorun ati Iwọ Oorun ni ko ni si ẹni ti yoo rọ wi pe ijọba fi ọwọ yẹpẹrẹ mu wọn.''

''Eyi ni pe ko si ibikibi ti awọn ọmọ Naijiria le wa ni agbaye, ti agbara ati ọrọ ti o tọ si wọn gẹgẹ bi ọmọ Naijiria ko ni de ọdọ wọn, to fi mọ aabo to tọ si wọn''

''Iwuri ni yoo si jẹ fun awọn ọmọ Naijiria lati kede pe ọmọ Naijiria ni awọn n ṣe''

Bakare fikun un pe idojukọ ti Naijiria n koju lọwọlọwọ n fihan pe ti Naijiria ba ni aarẹ to kunjuwọn, atẹgun ni idojukọ naa yoo jẹ.

''Igbagbọ mi ni pe ko si bi okunkun ṣe le pọ to, imọlẹ a tan lorilẹede Naijiria fun aye lati ri''

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

''Ohun ti a n koju lọwọ bayii ni pe nkan mẹrinlelogun ni a nilo ti yoo ṣi ọpọlọpọ ilẹkun fun wa, ti igba ọtun yoo si deba orilẹede Naijiria.

''Lati kekere mi ni mo ti ni awọn ẹrongba ohun ti ma a ṣe fun Naijiria lati mu ki Ariwa Naijiria ati Guusu di ọkan''

Pasitọ Tunde Bakare wa kesi awọn ọmọ Naijiria lati jẹ ki igba ọtun yii wa si imuṣẹ ti wọn ba dibo yan ohun.