You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Terrorism in Nigeria: Ìjọba àná lo jẹ Nàìjíríà run lórúkọ ìgbógun ti ìgbésùmọ̀mí - Malami
Agbẹjọro agba fun ijọba orilede Naijiria ati minisita idajọ Abubakar Malami ni àwọn ijọba ana lo sọ Naijiria di polofo nipa kiko owo na lorukọ pe awọn n gbogun ti awọn agbesumọmi.
O ni eyi ni nnkan akọkọ ti ijọba yii kọkọ ṣe lasiko ti ijọba naa bẹrẹ iṣẹ.
Abubakar Malami to jẹ agbẹjọro agba fun ijọba orilede Naijiria, ni ijọba ti o n bẹ lode yii lo fọ gbogbo idọti ijọba ana ti wọn se nipa kiko owo jẹ nipa gbigboun ti awọn agbesumọmi mọ.
Malami ṣalaye lasiko to n peju nibi eto ori radio kan ni ipinlẹ Kano.
- Kiní yóò sẹlẹ̀ si Àrẹ́mọ Ọ̀ọ̀ni Ile-Ife ti wọn ba gbé é kurò l'Áàfin
- A tún fẹ́ yá #12 Tiriliọnu náírà láti ilẹ́ òkèrè kí gbèsè Nàìjíríà di #50 tiriliọnu- BMO
- DDS ní kí n di ológbò bíi Sunday Igboho, ojú mi rí tó ní àhámọ́ DSS l'Abuja- Ifasooto
- Èyí ni ìdí tí Bàbá Kérésì fi máa n wọ aṣọ pupa àti funfun nígbà gbogbo
O n sọrọ lori awọn owo ti wọn ti ri gba pada, o salaye pe awọn ti ri apẹrẹ gbogbo awọn owo ti awọn n gba pada lawọn ilẹ okere, o si ti ran ijọba Muhammadu Buhari lati se onigbọwọ awọn isẹ akanse loriṣirṣi.
Adajọ agba naa tun ṣalaye pe eto gbigba nkan ini ilu pada lati ilẹ okere ti ṣe iranwọ nitori itiraka aarẹ Muhammadu Buhari lati koju iwa ikowojẹ eyi ti ko fi oju isaju tabi ipo ẹnikẹni wa lawujọ ṣe.
" Awọn owo ti wọn ti ji ko lati ẹyin wa paapaa julọ awọn eyi ti wọn ko pamọ si ilẹ okere ni wọn ti fi ṣe nnkan si Naijiria ti gbogbo eniyan si le ri kaakiri orilede Naijiria."
"Ọpọ awọn isẹ ti wọn ti fi owo naa ṣe ni opopona marosẹ Kano- Abuja, opopona Lagos Ibadan, Second Niger Bridge ti ọpọ awọn ijọba ati ẹyi wa ti n se ni ase pati, bakan naa oun ni an lo lati fun awọn ọmọ ile iwe ni ounje ti wọn si fi n san owo osu awọn ọmọ N-Power.
"Igbogun ti iwa jẹgudujẹra naa ti ni aseyori to pọ, ko si si oju isaju fun awọn to jẹ ọmọ igbimọ alasẹ gan pẹlu, ọpọ wọn lo koju idajọ ti ẹlomiran si foju kan ile ẹjọ.
" Bakan naa ni wọn tun gbogun ti eto aabo to mehe nitori ijọba ana ni orilede Naijiria bi wọn se ji ọpọ owo lorukọ pe awọn n gbogun ti iwa igbesumọmi ni Naijiria.
"Sugbọn nigba ti a de, gbogbo iwa ibajẹ ti wọn se silẹ ni a fi asiko wa fọ mọ, nitori naa a se gbogbo nkan ti wọn o ri se ni a se laarin ọdun kan."
" Ki a to de ijọba bi ijọba ibilẹ mẹtadinlogun ni o wa ni abẹ akoso awọn Boko Haram. Gbogbo ikọlu lo maa n waye ni gbogbo igba, sugbọn a ni ore ofẹ lati gba awọn ibilẹ mẹtadinlogun lo ti wa ni alafia bayii ti a si tun kọle fun awọn ti ko ri ile gbe.