Ekiti monarchs lead protest: Orí adé mẹ́rin ṣe ìfẹ̀hónúhàn l'Ekiti lórí ọ̀rọ̀ ìjọba ìbílẹ̀ wọn

Àwọn Ọba merin kan ni ijọba ibilẹ ilejemeje, nípìnlẹ̀ Ekiti tí dárí àwọn ará ìlú lati wọde onipẹlẹkutu láti fi ehonu han fún bí ìjọba apapọ àti ìjọba ìpínlẹ̀ kò ṣe ṣe nǹkan si olu ilé iṣẹ́ ijọba ìbílẹ̀ wọn ní Eda Oniyo.

Àwọn olórí ìlú náà ké gbajare ìyá àti ìdààmú tí wọn ń kojú ni agbègbè náà láti ìgbà tí wọn tí gbé oluleesẹ náà lati Iye Ekiti lọ si Eda Oniyo láti bí ọdún méjì sẹyin.

Wọn gbe oniruru awọn àkọlé lọwọ wọn, lara awọn akọle naa sọ pé olú ilé iṣẹ́ ijọba ibilẹ ìtọ́jú tó dára jù báyìí lọ "Olu ilé iṣẹ́ ìjọba ibilẹ yẹ kí o dára jù báyìí lọ" "Kò sí amojuto ìjọba kankan ní ìjọba ìbílè yìí," ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Àwọn Ọba tí ṣe ifẹhonu hàn ní alaga ìjọba ìbílẹ̀ Ilejemeje, ọba Elewu tí Ewu Ekiti, Oba Bamidele Adetutu- Ajayi, Ẹlẹda tí Eda Oniyo.

Oba Julius Awolola, Onijesha ti Ijeshamodu, Oba Aderemi Daramola, àti Onipere ti Ipere-Ekiti, Oba Omiyale Olufemi

Ọba Adetutu-Ajayi sọ pe ilé ẹjọ́ tó ga jù lọ paa láṣẹ pé kí wọn gbé olu ilé náà sí lọ sí Eda Oniyo ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Kejìlá ọdún 2018, Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ekiti náà pàṣẹ pé kí wọn ṣe àgbékalẹ̀ àwọn olóyè nínú oṣù Kẹ̀wá ọdún 2019.

"Ṣùgbọ́n títí di asiko yii ko si nnkan nílẹ̀ di àsìkò yìí, ilé lásán won ó kọ́ kalẹ, yàtọ̀ sí àwọn òṣìṣẹ́ àti ilé igbe tí àwọn ará ìlú pèsè, nítorí Eda Oniyo kò lè gbà gbogbo àwọn òṣìṣẹ́, èyí kò sì bojumu

Abẹ igi ni àwọn òṣìṣẹ́ náà tí máa ń ṣe iṣẹ́

"A ń rọ ìjọba ìpínlẹ̀ Ekiti láti fi tọkàntọkàn ṣe, kí ìjọba wà gba wa, kí wọn ṣàánú àwọn òṣìṣẹ́ tó ń lọ abẹ igi. A nílò kí wọn kò ilé tí yóò fi àmì hàn pé olú ilé iṣẹ́ ijoba ibile ni.

Àwọn Ọba náà ni àwọn tí kò ìwé orisirisi tó lè ní mẹ́fà sì ìjọba lai gba eso kankan. Kòdao tún gba ayé láti rí gomina bí ẹmẹẹta rí wọn kò sì dá esi padà di àsìkò yìí "

Alaga ijoba ibile Ilejemeje Oladunjoye Akinola ni nítorí kò sí ohun èlò tàbí àgbékalẹ̀ Ilé kankan, kò jẹ ki ìjọba ìbílẹ̀ náà lè ṣe ohunkóhun. Ó ní láti igba ti àwọn ti gbé olú ilé iṣẹ́ ijoba ibile naa wa si Eda-Oniyo, a ṣe gbogbo rẹ díẹ̀ díẹ̀ ni."

"Gomina Fayemi náà mọ nǹkan tó ń. Ṣẹlẹ̀ ni ìjọba ibile naa , a ti kọ̀wé ranṣẹ pé a fe kọ ọfiisi a sì ń retí kí ìjọba buwọ́lu"