Bauchi State: Okú 596 ló ṣì ń gba owó oṣù

O kéré tán ènìyàn mẹrindinlẹ́gbẹ̀ta ló ṣi n wà lórí ìwé ti wọ́n fi n san owó oṣù òṣìṣẹ́ ìjọba ti wọ́n si n gba gbogbo àjẹmọnú wọ́n ni ìpínlẹ̀ Bauchi, gẹ́gẹ́ bi ìgbìmọ̀ ìwádìí ṣe sọ.

Ìròyìn ti sọ ṣááju pe ni ìjọba ipinlẹ Bauchi, o dín díẹ̀ ni eniyan ẹgbẹ̀run méjìlélógójì tó wà lóri iwé owó osù ìjọba lai ni BVN.

Góminà Bauchi, Bala Muhammed wá ṣe àgbékalẹ̀ ìgbìmọ̀ ẹlẹni mẹ́tàdinlógun láti tú iṣu dé ìsàlẹ ìkòkò lóri bi ọ̀rọ̀ náà ṣe jẹ́.

Alága ìgbìmọ náà, Adamu Gumba lásìkò to n ba àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ lóri abájade ìwádìí ìgbìmọ̀ rẹ̀ lọ́sàn òní ló fi ọrọ yii lede.